AYE ASAN
Jesu Kristi kilo fun awon omo ehin re ki won wa ni imura sile fun gbigba awon eniyan mimo soke. Mesaya so wipe sugbon e maa kiyesara yin, ki okan yin ki o ma se kun fun wobia, ati oti amupara, ati fun aniyan aye yii, ti ojo naa yoo si fi de ba yin lojiji bi ikekun. Nitori bee ni yoo de ba gbogbo awon ti ngbe ori gbogbo ile aye. Nje ki e maa sona, ki e si maa gbadura nigba gbogbo ki e baa le la gbogbo nkan wonyi ti nbo wa se; ki e si le duro niwaju omo eniyan
(Luku 21: 34-36).
EKO
Iseto aye ni ki awon eniyan gbaju mo ohun ofo aye yi ti yio mu ki won kuna sisin olorun lotito. Ipenija nihin ati lohun gbese wa lati san, ati orisirisi ojuse to tona ni sise. Kristeni ni lati kiyesara ki ohunkohun ma se ba idapo won pelu olorun je.
Bi aye fe, bi aye ko, igbasoke yio sele, ti Jesu kristi yi o gba awon eni mimo lo sorun. Eni keni ti o ba ku yi o je iya nla lati owo idaloro satani. Nitorina gbogbo eniyan nilati mura sile fun igbasoke pelu Jesu Kristi nigba ti yi o fara han ni ofurufu.
ADURA
Asan lori asan, aye yi asan ni. Mo ti pinu lati tele Jesu Kristi, ohunkohun ko ni mu mi ye ijeri mi. Mo si ti sepinu lati duro ti eri mi gege bi omo olorun. Mo duro ti oro mi, emi yio si di ijewo Jesu Kristi mu titi dopin. Beni Jesu Kristi nikan ni omo olorun nitooto ti a ran lati gba elese to sonu la. Nigba ti mo gbagbo ninu Jesu, a dari ese mi ji mi, mo si yege fun igbasoke. Jesu Kristi ni oluwa ati olugbala mi, satani ko le se idina/idaduro mi. Igbagbo mi wa ninu omo olorun titi aye. Amin.
