IDAJO
Dafidi fi igbe aye re wewu nipa jija fun orile-ede re bi o se pa Goliati, a ko san an lesan to joju. Oba Saulu ti o ye ki o kun fun ayo fun aseyori Dafidi ti wa kun fun jijowu, o si fe paa ni gbogbo ona. Bi Dafidi ti nsa fun emi re, o ni lati sun ni aginju iberu fun ojo meta, ti o nreti abo ireti re lo jasi. Bibeli salaye bi Jonatani se gbiyanju bi Dafidi yio o se bo lowo igbogun oba Saulu. Nigba naa ni Jonatani wi fun Dafidi pe ola ni osun titun, a o si fe o ku, nitori ti ipo re yi o sofo. Bi iwo ba si duro ni ijo meta, nigba naa ni iwo o si yara sokale, iwo o si wa si ibi ti iwo gbe ti fi ara re pamo si nigba ti ise naa wa lowo, iwo o si jokoo ni ibi okuta eseli. Emi o si ta ofa meta si iha ibe naa, gege bi eni pe mo taa si ami kan. Si woo, emi o ran omodekunrin kan pe, lo ki o si wa ofa won-ni. Bi emi ba tenu mo o fun omọkunrin naa pe, woo, ofa won-ni wa lehin re, sa won wa nigba na ni iwo omaa bo, nitori ti alaafia nbe fun o, ko si ewu, bi Oluwa ti wa. Sugbon bi emi ba wi bayii fun omodekunrin naa pe, woo, ofa naa nbe niwaju re, nje maa ba tire lo, Oluwa ni o ran o lo niti oro ti emi ati iwo si ti jumo so, woo ki Oluwa ki o wa laarin iwo ati emi titi lailai. (1Samueli 20: 18-23).
EKO
Eto ti aye ni lati yeye olotito ki won si bola fun eniyan buburu, iru eto buburu le wa sugbon kii pe lo titi. Olorun yi o se idajo eniyan buburu lori iwa buburu re. oludajo ododo yi o bola fun awon eniyan ti a fi owo ola gba won loju tabi awon ti a re je ni aye. Yi o fun won ni ipo to ga ninu ijoba re. kii se fifun awon olotito ni ibukun ni orun, olorun yi o bukun won ni aye pelu. Yi o ri wipe awon ti o ba duro tii ni aye, a ki yio doju ti won.
ADURA
Olorun olufe, jowo bukun mi koja inunibini ati ininilara awon ota mi lo. Je ki imole ogo re tan le mi lori, ki oju mi si ma fi ewa re han. Bukun mi ni aye ati ni orun ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
