ATONA WA
Emi-Mimo dari Filippi ki o rin irin ajo lo ninu aginju, ki o bale waasu fun okunrin kan ti o npongbe lati mo nipa Jesu Kristi. Bibeli so wipe ‘Angeli Oluwa si so fun Filippi pe, dide ki o si maa lo si iha gusu ni ona ti o ti Jerusalemu lo si Gasa tii se iju. Nigba ti o si dide, o lo si kiyesi okunrin kan ara Etiopia, iwefa olola pupo lodo kandake obabinrin awon ara Etiopia, eni ti nse olori gbogbo isura re, ti o si ti wa ni Jerusalemu lati josin. Oun si npada lo, o si joko ninu keke re, o nka iwe wolii Isaiah. Emi siwi fun Filippi pe, lo ki o si dara re po mo keke yii.
(Awon Aposteli 8:26-29)
EKO
Emi-Mimo je atona Olorun si onigbagbo, enikeni ti o ba faye gbaa ninu aye re ko ni ri ijakule sugbon yi o ni aseyori. Emi Olorun a maa sise ni orisirisi ona, o si lee dari kristieni lati se awon ise ti o yato, Emi-Mimo yi o se amona enikeni ti o ba te Olorun lorun, ko si ni tako Bibeli. Ise iyanu a maa sele nigba ti kristieni ba gba itoni Emi-Mimo, awon eniyan nri igbala, iwosan, igbagbo, idaniloju ati awon ise iyanu miran gba. Olorun maa nyayo nigba ti awon omo re ba gboran si idari Emi-Mimo, lakotan a le so wipe ko lee si abamo ti a ba gboran si itoni ati idari Emi-Mimo, a o maa segun nigba gbogbo, esu ni yi o maa padanu.
ADURA
Olorun olufe, ko mi bi mo se maa gboran si idari Emi-Mimo, je kin kun fun adura pelu ikiyesara, kin le ni oye ohun ti Emi ba nba mi so. Se mi ni iranse ti o ni ikiyesara ti o ngboran si imoran, je ki igboran mi se ijoba re ni anfani, mase je ki nkabamo wipe mo nsin o sugbon je kin se aseyori ni aye yi ati ni orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
