GBEKELE OLORUN
Olorun untoju awon omo re, o si undabo bo won kuro lowo ota won. Ota ti o ba hale mo awon omo Olorun ti di ota Olorun, o sin fi ina sere. Dafidi mo eyi nigba ti o so ninu orin wipe ’Ki Olorun ki o dide, ki a si tu awon ota re ka, ki awon ti o korira re pale, ki won ki o salo kuro ni iwaju re. Bi eefin tii fe lo be ni ki o fe won lo, bi ida ti yo niwaju ina beeni ki eniyan buburu ki o segbe niwaju Olorun. Sugbon je ki inu awon olododo ki o dun ki won ki o yoo niwaju Olorun, nitooto ki won ki o yo gidigidi.
(Orin Dafidi 68:1-3)
EKO
Olorun ni ota, awon ota re ni awon eniyan ati agbara ti o unhale mo awon kristieni. Eleda ko ni inu didun si awon ota sugbon yi o lo pelu gbogbo ipa lati da bobo ife re ninu aye awon omo re, ogun ti Olorun ba ja, awon eniyan maa di ode, abajade re maa nkoja oye okan eniyan. Nitori na omo Olorun nilati ni igbekele ninu Olorun, ki won ke pee lati gbeja won ni akoko isoro won.
ADURA
Mo pase ki Satani siwo dida mi laamu nitori mo gbe ina Olorun, mo segun gbogbo ipa ota ninu aye mi ni oruko Jesu Kristi. Niwon bi mo se je omo Olorun, ogun mi je ogun Olorun, awon ota mi si je ota Olorun. Mo pe agbara Olorun sori gbogbo ihale ota ni gbogbo ona mi, ki won si yo bi ori niwaju ina, mo kede ogun le awon ota mi lori, mo si fi ipa mu won lo si iporuru okan, mo paa run gbogbo ete won, mo si so agbara won di ofo. Mo so awon oro wonyi jade pelu ase ni oruko Jesu Kristi. Amin.
