TITOBI AGBARA OLORUN II
Enikeni ti o ba gbekele Olorun ko ye ki o beru ota, o ye ki o ye wa wipe abo Olorun ko see dalu tabi la koja. Iru agbara yi kose bori, Dafidi oba mo pataki agbara Olorun, o si unyo ninu abo re, Dafidi wipe ‘Oluwa ni imole mi ati igbala mi, tani emi o beru, Oluwa ni agbara emi mi, aya ta ni yoo fo mi? nigba ti awon eniyan buburu ani awon ota mi ati awon abinuku mi sunmo mi lati je eran ara mi, won kose, won si subu. Bi ogun tile doti mi, aya mi ki yoo ja, bi ogun ti le dide si mi, ninu eyi ni okan mi yoo le.
(Orin Dafidi 27:1-3)
EKO
Agbara Olorun tobi, ko si see bi subu nipa agbara miran. Olorun yi o dab obo eniyan, ibugbe tabi ipo, yi o dabo bo ara re yi o si yin oruko re logo, eleda ko si ni pin agbara unla re pelu enikeni yala, yi o fi Satani si abe ese re. Yi o si se ara re logo ninu aye awon omo re, nitori naa, gbogbo eniyan ni lati gbiyanju lati di omo Olorun, nitori yi o ni anfani lati je igbadun abo ati ipese.
ADURA
Olorun olufe, mo sasi abe ago abo re, jowo se mi ni ayanfe omo re, ki o si se alabo mi kuro lowo ota ti npani run. Mo odi abo re yimika, ki o si dabo bomi ni gbogbo igba. Dabo bo mi kuro lowo ofa ota ti nfo losan ati ni oru, ki nsi wa goke ninu agbara ati aseyori. Jowo jeki enu mi kun fun eri didara re ni gbogbo igba. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
