JESU NI AGBARA IYE
Lasaru ku nitori aisan unla a si sin, sugbon Jesu Kristi wa ni ojo kerin o si ji dide, Jesu ti a ti so fun nipa ailera Lasaru dese duro imularada re ki Satani lee se eyi ti o buru ju. Olugbala setan lati yeye Satani ki o si se ara re logo, Jesu Kristi ti so ero re fun arabinrin Lasaru (Maria) nigba ti o wipe ‘Jesu wi fun un pe, emi ni ajinde ati iye, eni ti o ba gba mi gbo, bi o tile ku, yio ye. Enikeni ti o nbe laaye, ti o si gba mi gbo ki yoo ku laelae, iwo gba eyi gbo?
(Joanu 11:25-26) Nigba kan na, Lasaru ku, Jesu wa ni ilu lati jii dide. Hallelujah
EKO
Satani wonu wahala nitori Jesu Kristi ni agbara lori oku, eyi ti o buru ju tiota le se ni ki o pa eniyan sugbon Jesu ni agbara lati fun wa ni iye. Agbara Satani kere si agbara Jesu Kristi, ni opin ojo Jesu yi o ji awon onigbagbo ti o ti ku dide, yi o si ran wan lo si orun. O seni laanu pe Satani ati awon omo lehin won yi o wa titi lae ni orun ina apadi, won o ma joro ninu ina ti ko ni ku laelae, won o ma da won loro titi lae lae loosan ati ni oru. Gbogbo enikeni ti o ba gbagbo ninu Jesu Kristi yi o janfani Alafia ati oro Olorun ni orun rere titi aye.
ADURA
Eyin Jesu logo mo ti di atunbi, mo unlo si orun rere, emi ko ni lo si orun ina apadi, nitori mo je omo lehin Jesu Kristi. Orun ni ile mi, emi o si gbadun re titi laelae. Niwon igbati Jesu ti segun satani nipa iku ati ajinde ni nkan bi egberun odun meji o le die sehin. Mo jewo aseyori ati isegun mi ninu re, satani ko ni agbara lori mi mo. Mo di ominira kuro lowo egun ese ati iku titi laelae. Beeni mo di ominira, beeni Jesu Kristi ti so mi di ominira nitooto. Amin.
