IYE NINU KRISTI
Jesu Kristi mo riri awon omo lehin re pelu ola nla. O wipe ‘Awon aguntan mi ngbo ohun mi, emi simo won, won a maa to mi leyin. Emi si fun won ni iye ainipekun, won ki o si segbe laelae, ko si eni ti o le ja won kuro ni owo baba mi.
(Johanu 10:27-28)
EKO
Abo to daju to si peye ju ni ki a ni iye ninu Olorun, Jesu Kristi fi ye awon omo ehin re wipe oun yi o fun won ni iye ayeraye. Niwon igba ti Jesu Kristi ti yonda aye re lati ku ti o si ji dide, yi o si se be fun awon ti o ba tele. Awon omo lehin Jesu yi o ku nigba kan, won o si ji dide lati ni iye ainipekun ni orun, bakan naa awon alaigbagbo yi o ku nigba meji. Iku ti aye ati iku ti ayeraye ni orun apadi, nigba ti Jesu Kristi seto abo iye ayeraye to lo si orun, gbogbo eniyan ni lati wa si abe iso abo re.
ADURA
Jesu olufe, ina orun apadi ti gbona ju emi ko si fe lo sibe, emi ko fe fi se ibugbe ayeraye. Mo fe lo si orun nibi alafia pipe, nibi ti ko si irora tabi eebu, orun ina apadi kun fun eeru sugbon alafia wa ni orun rere. Mo setan lati fi ola ati ayanmo mi fun o, ki emi le lo si orun rere, loni, mo pinu lati fowo si eto abo re ti ko ni ye laelae. Mo jewo Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala mi, mo si fi gbogbo aye mi fun o, emi yi o sin o pelu okan mi, emi o si rohin iriri igbala mi pelu awon eniyan. Ki Olorun ran mi lowo. Amin.
