AGBODO SUNMO OLUWA
Okunrin tabi obinrin ti o ba beru Olorun yi o je igbadun re, iru eni bee yi o gba itoni Olorun ati abo to daju. Orin Dafidi wipe ‘Okunrin wo ni o beru Oluwa, oun ni yi o ko ni ona ti yoo yan, okan re yoo joko ninu re, iru-omo re yoo si jogun aye. Asiri Oluwa wa pelu awon ti o beru re, yoo si fi won mo majemu re.
(Orin Dafidi 25:12-14)
EKO
Ti a ba sunmo Olorun, oun yi o sunmo wa. Olorun maa nwa ona lati bukun awon omo re, sugbon o seni laanu wipe awon eniyan kan pinu lati jina sii, nitori naa won ko le je ninu anfani re. Die ninu awon ti o nrin dede pelu Olorun unje orisirisi anfani re, o ye ki gbogbo eniyan sunmo Olorun, ki a ni idapo to dara pelu re, ki o le dara fun wa ki oju le ti Satani.
ADURA
Olorun olufe, mo loye pe awon eniyan ti o ba sunmo o nje opolopo anfani re, mo si fe maa je won lati akoko yi lo. Mo pinu lati sunmo o ju ti atehin wa lo, emi yi o jawo fifi akoko ati agbara mi sofo lori awon ohun ti ko se mi loore, un o fi kun idapo laarin emi ati Olorun. Emi yi o yin o ju ti tele lo, un o si sin o, jowo fun mi ni ore-ofe lati mu ileri mi se, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
