AGBODO TELE JESU
Jesu Kristi ni ona kan soso ti o lo si orun. Ko si ona miran ti o lo si Olorun bikose nipase Jesu Kristi. Olugbala wipe ‘looto looto ni mo wi fun yin, eni ti ko ba gba enu ona wo inu agbo aguntan sugbo ti o ba gba ibomiran gun oke, oun naa ni ole ati olosa. Sugbon eni ti o ba ti enu-ona wole, oun nii se Oluso awon aguntan. Oun ni Oludena silekun fun, awon aguntan si gbo ohun re, o si pe awon agunta tire ni oruko, mo si se amona won jade. Nigba ti o si mu awon aguntan tire jade, O siwaju won, awon aguntan sin too leyin, nitori ti won mo ohun re… Emi ni Oluso-aguntan rere, oluso agunta rere fi emi re lele nitori awon aguntan. (Johanu 10;1-4 & 11).
EKO
Opolopo elesin ti wa lode, opolopo eniyan (oku tabi alaye) ni won wipe awon ni iranse Olorun ti o ran wa sile aye lati wa gba araye la. Ko si eni ti o ni eri bi Olugbala, afi Jesu Krist. Jesu so wipe oun nikan ni ona ti o lo sodo Olorun, o si ni eri fun gbolohun yi. Oku, o si ji dide lehin ojo keta, O si seleri lati ji dide gbogbo awon ti o ba gbaa gbo ni ojo ikehin. Ani igboya lati tele eni ti o ti ko iku wo ti o si ji dide nigba kan naa. Bi a ba tele Jesu krist, a o to ajinde wo lehin iku. Nitorina enikeni ti o ba gba Jesu ni Oluwa ti o si gbaa gege bi Olugbala yi o di eni igbala.
ADURA
Mo fi gbogbo aye mi fun Jesu Kristi looni, mo si gbaa gege bi Oluwa ati Olugbala mi. Niwon igba ti o je wipe Jesu Kristi ni ona kansoso ti o lo si orun, emi yi o duro gidi pelu re. Emi ko ni dese mo, ko si idapo pelu esu mo. Latoni lo, igbe aye mi je ti Olorun, emi o si maa sin o titi aye, Amin.
