ONIGBAGBO GBODO JE ENI TI O LE KO RA RE NI IJANU
Jesu Kristi fi ye wa eredi iwa bi Olorun ati ikora eni ni ijanu je awon amuye fun ijoba Olorun. Jesu wipe ‘Bi enikeni ba nfe lati maa to mi leyin, ki o se ara re, ki o sigbe agbelebuu re ni ijo gbogbo, ki o si ma to mi leyin. Nitori enikeni ti o ba fe gba emi re la, yoo soo nu, sugbon enikeni ti o ba so emi re nu nitori mi, oun na ni yoo si gba a la. Nitoripe ere kini fun eniyan bi o jere gbogbo aye, ti o so ara re nu, tabi ki o fi ara sofo. Nitori enikeni ti o ba tiju mi, ati oro mi, oju re ni omo-eniyan yoo si ti, nigba ti o ba de inu ogo tire ati ti baba re, ati ti awon angeli mimo.
(LUKU 9:23-26).
EKO
Enikeni ti o ba pe ara re ni kristieni tooto nilati wa ni ikoraeni nijanuki o si tele Jesu ninu awon eko ti o wa nisale wonyi.
* Kristieni tooto ni lati ni irepo timotimo pelu Olorun lojoojumo (bi enikeni ba nfe lati maa to mi leyin, ki o se ara re, ki o si gbe agbelebu re ni ijo gbogbo, ki o si maa to mi leyin Luku 9:23)
* Kristieni tooto ni lati fi ihinrere yangan ki o si ma wasu fun gbogbo eniyan. Nitori enikeni ti o ba fe gba emi re la, yoo soo nu, sugbon enikeni ti o ba so emi re nu nitori mi, oun na yoo si gba a la (LUKU 9:24)
* Kristieni tooto ni lati wadi ohun gbogbo ki o si di eyi tin se otito mu, nitori pe ere kin ni fun eniyan bi o jere gbogbo aye ti o si so emi re nu tabi ki o fi ara re sofo (LUKU 9:25)
* Kristieni tooto nilati fara mo ikoni inu bibeli, asa ibile re ba tile takoo, nitori enikeni ti o ba tiju mi, ati oro mi, oju re ni omo-eniyan yoo si ti, nigba ti o ba de inu ogo ti baba re, ati ti awon angeli mimo (LUKU 9:26)
ADURA
Olorun, jowo ran mi lowo lati je kristieni ti nkora re ni ijanu ti o sinlepa ohun iwa bi Olorun. Je kin di oku si ese ati awon aisododo gbogbo. Ran mi lowo lati leja ija igbagbo, bi o se fe ki nba le yo fun ijoba re ayeraye ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
