ONA OLORUN KORI BI ONA TIWA
Saulu fara sin fun ebi re, o nwa ketekete baba re ti o sonu, sugbon Olorun ni eto nla fun, Olorun ni ki Wolii Samueli fi ororo yan Saulu gegebi Oba kini awon Isreali. Itan ainigbagbo na lo bayi ‘Oluwa ti wi leti Samueli ni ijo kan ki Saulu ki o to de, wi pe niwoyi ola emi o ran okunrin kan lati ile Benjamini wa si o, iwo osi da ororo sii lori ki o le je olori ogun Isreali awon eniyan mi, yoo si gba awon eniyan mi la lowo awon Filistini, nitori emiti bojuwo awon eniyan mi, nitori igbe ekun won ti de odo mi. nigba ti Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun pe, wo okunrin naa ti moti soro re fun o, oun ni yoo joba awon eniyan mi. (Samueli kini 9:15-17).
Samueli si mu igo-ororo, o si tuu sii ni ori, o si fi enu koo ni enu, o si wipe, ko se pe nitori ti Oluwa ti fi ororo yan o ni olori ini re (Sameuli kini 10:1)
EKO
Ona Olorun yato si tiwa, O le feya wa lenu lona ti a ko reti rara, ko si enikeni ti o le de Olorun sinu apoti. A ko si le se odiwon re pelu oye kekere wa. Olorun yi o se ohun ti o ba pinu lati se, ko si ohun ti o le yi ilana re pada. Eero Olorun si awon omo re daradara ni. O wipe ‘Mo mo ero ti mo ro si yin ni Oluwa wi, ani iro Alafia, ki i se si fun ibi, lati fun ni igba ikeyin ati ireti (Jeremiah29:11) sugbon ero Olorun le ma wa si mimuse ni pipe ninu aye wa bi aba se aigboran si ofin re.
ADURA
Olorun olufe ran mi lowo lati le duro ninu eto re fun mi, ki emi le je anfani ore-ofe re ati didara re. je kin le maa te o lorun nigba gbogbo, kinsi ye fun ibukun re. jowo ranti gbogbo awon ileri re ki won wa si imuse. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
