OLORUN YIO DA O NIDE
Orile ede Babeli ti ni Israeli lara fun opolopo akoko, Olorun so wipe, oun fe lati dawon duro. Olorun soro nipase Jeremiah ‘yio si se ni ojo naa, ni Oluwa awon omo ogun wi, tiemi o si se ajaga kuro ni orun re, emi o si ja ide re, awon alejo ki yio si mu o sin won mo. Sugbon won o maa sin Oluwa Olorun won, ati Dafidi Oba won eni ti emi o gbe kale fun won. (Jeremiah 30:8-9).
EKO
Olorun yio fi awon Omo re si okan, yio ranti ife re si won, yio si dari ese won ji won. Eledaa yio gba awon omo re lowo idaloro ti Satani le fi doju ko won. Nigba ti oruko re je Jehovah Nissi (Olorun Oluwosan) yio lo gbogbo agbara lati gbeja awon omo re. O wa je ohun ti o dara, ki gbogbo eniyan sun mo Olorun, ki won si di omo re. Ona lati di omo Olorun rorun ki iru eni bee ki o jewo Jesu Kristi gege bi omo Olorun ni tooto ki o sig baa ni Oluwa ati Ougbala re. Logan ti Jesu ba ti gba iru eni bee, yio fi idi re mule o ti di omo Olorun, o si ye fun abo to peye ati awon ibukun.
ADURA
Olorun Olufe, mo mo pe iwo ni Olorun alagbara julo, o ni agbara lati le se ohun gbogbo. O si se ohun gbogbo ti ba ye lati se abo, ife awon omo re. Nitori naa, mo fi aye mi fun o looni. Mo yonda aye mi lati di omo re, mo jewo wipe Jesu Kristi nikan ni omo re, ti a ran lati gba araye la, mo gbaa sinu aye mi gege bi Oluwa ati Olugbala mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye ki nsi bere si ni je anfani ipese ati abo re lati akoko yi lo. Ni oruko Jesu Kristi omo re ni mo beere. Amin.
