OLORUN NRII O SI MO OHUN GBOGBO
Iwa buburu je eewo si Olorun, ko si eniyan buburu ti yio lo lai jiya (elese kan ko ni lo lai jiya). Bibeli salaye awon ika eniyan, O wipe won pa won opo ati alejo, won si pa awon omo alaini-baba. Sibe won wi pe, Oluwa ki yio rii beeni Olorun Jakobu ki yio kaa si. Olorun yio san esan fun eniyan buburu fun ise ibi won. A koo wipe, ki oye ki o ye yin, eyin ope ninu awon eniyan, ati eyin asiwere, nigba wo ni eyin o gbon? Eni ti o da eti, o le se alaigbo bi? Eni ti o da oju, o ha le se alairiran? Eni ti n na awon Orile-Ede, o ha le se alaise oluto? Oun ni eni ti nko eniyan ni imo. (Orin Dafidi 94:8-10)
EKO
Olorun nri, o si mo ohun gbogbo, yio san esan fun eniyan buburu pelu ijiya nla, ayafi bi won ba ronupiwada. Olorun Eledaa yio bukun awon ti o beru Olorun, yio bukun won ni aye, yio si pese ibujoko ti o dara ju fun won ni orun. Nitori eyi, a nro gbogbo eniyan ki won beru Olorun, ki won si se dara dara si ara won, ki won bale ye fun ibukun Olorun.
ADURA
Olorun Olufe, mase ka mi mo awon onise buburu, nko fe ki a pin mi pelu ika eniyan. Je ki emi feran re ki nsi beru re ni gbogbo igba. Je ki emi si feran awon eniyan bakannaa. Jowo bukun mi looni, ni ola ati ni gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
