OLORUN MO OHUN GBOGBO
Olorun mo ohunkohun ti enikokan wa ba nse. O mo ero okan ati isesi wa, yi o si da wa lohun bi o ti ye, orin Dafidi salaye, awamaridi ati wiwa nibi gbogbo ti Olorun o wipe ‘Oluwa, iwo ti wadi mi, iwo si ti mo mi, iwo mo ijoko mi ati idide mi, iwo mo iro mi ni ona jinjin rere. Iwo yi ipa ona mi ka ati idubu le mi, gbogbo ona mi si di mimo fun o nitori ti ko si oro kan ni ahon mi, kiyesii Oluwa iwo mo on patapata.
(Orin Dafidi 139:1-4)
EKO
Enikeni ti o ba ro wipe oun le sa pamo lodo Olorun nse awada, ko si eni ti o le fara pamo fun Olorun, niwon bi o ti wa ni ibi gbogbo o si mo ohun gbogbo. Oju Olorun riran daradara ninu okunkun, wiwa re si nbe ni ibi ti eniyan ko ti le duro, niwon bi Olorun ti je alagbara bayi o ye ki gbogbo eniyan beru re, ki won si jowo ara won fun un. Gbogbo eniyan ni lati mo nipa oju Olorun ti o wa nibi gbogbo, ki a to se ohun kohun, (Olorun yi o se idajo, san esan fun ohun gbogbo, ibaa se rere tabi buburu).
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe o mo ohun gbogbo, o si nri ohun gbogbo oo si se idajo ohun gbogbo, je ki emi naa te o lorun ninu ero mi ati isesi mi, ki emi ma ba se si o. Fun mi ni ore-ofe lati te o lorun ninu ohun gbogbo, ki emi lee se rere ni ile alaaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
