OLORUN MAA N SAN ESAN IGBORAN
Kristeni gbe Olorun wo sinu ara won, a ko gbodo bii ninu. Bibeli wipe Eyin ko mo pe tempili Olorun ni eyin i ise, ati pe Emi Olorun ngbe inu yin. Bi enikeni baba tempili Olorun je, oun ni Olorun yio parun nitori pe mimo ni tempili Olorun, eyi tie yin je (1 Korinti 3:16-17)
EKO
Awa eda eniyan ko ni ase lori ago ara wa, sugbon Olorun ni ase. Nitori naa, gbogbo Kristeni ni lati mo wipe a je tempili Emi Mimo ti Olorun, ki a si fi iberu toju re. Ki a kiyesi ohun ti a nse si ara wa. Ki a toju re daradara ninu iwa mimo. O ye ki a fenu baa wipe ese ibalopo nba ara ati emi je, won so wa di ota Olorun. A ni lati yera fun ese ibalopo ti nse ara lese, ati awon ohun ti a le pe ni eewo, ki a le yin Olorun logo ninu aye wa.
ADURA
Olorun Olufe, mo kaanu bi mo se lo ara mi ni ilokulo. Mo wa ni imo baayi pe, ago ara mi je tempili re, emi ko si gbodo baa je. Emi yio pa ara mi mo fun ogo re. Je ki emi maa ranti pe, iwo yio se idajo gbogbo ara ti mo lo ni ilo egbin. Je kin le pa ago ara mi mo ni mimo, ki emi ma baa gba idalebi ni ojo idajo. Ran mi lowo lati le je olotito, ki nsi di idapo mi pelu re mu daradara, ni gbogbo ojo aye mi, ki emi le wo inu ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
