OLORUN KII SE OJUSAJU
Dafidi Oba wo ehin wo, o wa rii wipe Olorun je ki oun se aseyori laisi alatilehin tabi iriri. Oba rii wipe a ko bii si ile ola, bakannaa ko si ohun to ye fun aseyori lara re. Sibe Olorun yan an fun aseyori nla, nigba to femi re wewu lati pa Goliati, ti o si ja fun orile-ede re (o si gbe oruko Olorun ga). Olorun so darandaran di oba, o si soo di alaseyori nla. Dafidi wa pinu lati re ara re sile, nigba ti o ranti pe oun ko je nkankan ki Olorun to soo di eni Pataki nla. Oba re ara re sile, o wipe, Oluwa, Oluwa wa, oruko re ti ni iyin to, ni gbogbo aye, iwo ti o gbe ogo re ka ori awon orun. Lati enu awon omo-owo ati omo-omu ni iwo ti se ilana agbara, nitori awon ota re, nitori ki iwo ki o le mu ota Olugbesan nni dake jee.
(Orin Dafidi 8:1-2).
EKO
Olorun kii se ojusaju, o nlo, o si yin bukun enikeni ti o kogo ja niwaju re. Ko se iparo oloro si talaka, ko si kaanu talaka fun ipalara oloro. Olorun yi o lo enikeni ti o ba yonda ara re fun un, boya Oloro tabi talaka. Eni ti Olorun ban lo se ori-re. Iru eni bee yi o gba ibukun repete. Enikeni ti o ba di ohun elo fun ise Pataki fun Olorun, yi o gba opolopo ibukun ati ola ti yi o si tun je ti awon omo re ati iran ti o unbo. (E ku orire eyin ti e ti yonda ara yin fun elo Olorun, nitori pe won o di eni ibukun).
ADURA
Olorun Olufe, jowo lo mi, mo mo wipe iwo yi o bukun mi bi mo ba yonda ara mi fun lilo re. Nitorinaa mo yonda ara mi fun lilo re lati akoko yi lo, emi yi o se ohunkohun ti o ba fe ki emi se; emi o si se daradara. Jowo je ki oro-ofe ati agbara re fara han nigba ti mo ba gboran si ase re, si je ki emi se aseyori ninu ise iranse mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere.Amin.
