OLORUN DAWA L’AWORAN RE
Awon eniyan nikan ko ni Olorun da, awa ko ni a rewa ju tabi ni agbara ju. Olorun da awon Angeli ti won ni agbara ti a ko le fi we tiwa, bi agbara ti kere to ni Olorun se wa ni oso, ti a fi ni ola ju awon Angeli ati awon eda to ku lo. Dafidi se ayewo aile salaye bi Olorun se da omo eniyan o wipe ‘Oluwa, kin ni eniyan ti iwo fi nkiye sii, tabi omo eniyan ti iwo fi nronu re, eniyan dabi asan, bi ojiji ti nkoja lo ni ojo re. (Orin Dafidi 144:3-4) Dafidi tun wipe ‘Nigba ti mo ro orun re, ise owo re, osupa ati irawo, ti iwo ti se lana sile. Kini eniyan, ti iwo fi nse iranti re? ati omo eniyan ti iwo fi nbee wo, iwo sa daa ni onirele die ju Olorun lo, iwo si ti fi ogo ati ola de e ni ade. Iwo mu un joba ise owo re, iwo si ti fi ohun gbogbo sabe ese re, awon aguntan ati maaluu pelu ati awon eranko igbe, awon eye oju orun ati awon okun, ti o nkoja lo nipa ona okun, Oluwa Oluwa wa, oruko re ti ni iyin to ni gbogbo aye!
(Orin Dafidi 8:3-9)
EKO
Omo eniyan ni ohun ti o dara ninu gbogbo alaaye ti a da, Olorun ti o je eda agbaye pinu lati da eniyan ni aworan ara re. Olorun soro pelu ase wiwa laaye awon ohun ti o da, o wonu ise sise nigba dida eniyan, Olorun bere o si lo owo re lati mu amo lati mo ori eniyan, owo, apa, imu ati eya ara ti o ku. O si tun dobale ki o ba le mi imisi si ohun ti ko ni emi ti o sese mon, eniyan di alaaye, o wa dabi Olorun. Olorun si pin jijoba re pelu eniyan ti o sese da, o si ni ki o maa sakoso lori awon eda yoku, Olorun je iyanu si eniyan ati awon iran to tele. Olorun ti se nkan nla fun iran omo eniyan, gbogbo wa ni lati mo riri ore nla yi, Olorun fi ife nla re han o si ye ki a fi imore wa han, gbogbo eniyan ye ki a maa yin Olorun nitori ti o da wa ni eniyan, a kii se eranko. Niwon bi Olorun se bu ola fun wa, o ye ki a bu ola fun un, gbogbo eniyan nilati dupe fun Olorun fun iseda won.
ADURA
Olorun olufe, mo dupe nitori o da mi ni eniyan, o sese ki o dami ni adiye, enikan iba ti fi mi se ounje ale. O ko da mi ni eja ti elomiran iba ti pa je, o da mi ni eniyan o si fun mi ni ewa, ore-ofe ati ola, mo jewo pe iyanu eleda ni o. Mo feran re pupopupo, mo si mo riri ise re, emi o si lo iyoku aye mi lati maa yin o, emi yi o yin o ni aaro ati ni asale, kii se eyi nikan emi yi o sin o ni igbagbogbo fun iyoku igbe aye mi. Jowo di mi mu ki nle sin o ni otito titi de opin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
