OFIN ATI ILANA OLORUN KII YE
Olorun ka aigboran Isreali si ese nla, O si seleri lati mu won jiya bi won ba ko lati ronupiwada. Olorun soro nipase Jeremiah ‘Bayii ni Oluwa Olorun Isreali wi, ifibu ni Oluwa re ti ko gba oro majemu yii gbo. Ti mo pa ni ase fun awon baba yin, ni ojo ti mo mu won ti ile Egipti jade lati inu ileru irin wipe, gba ohun mi gbo, ki e si se gege bi emi ti pase fun yin. Bee ni eyin o je eniyan mi, emi o si je Olorun yin, ki emi ki o le mu ileri mi se, ti mo ti bura fun awon baba yin lati fun won ni ile ti nsan fun wara ati fun oyin, gege bi o ti ri ni oni, mo si dahun mo si wipe Amin, Oluwa.
(Jeremaya 11:3-5)
EKO
Olorun ni awon ofin ti a ko le yipada, awon ofin yi se koko sugbon o rorun. Orun fi idi re mule pe a nilati yera fun ese. A nilati feran re, ki a si feran awon aladugbo wa, ti a ba gboran si Jehofa yi o bukun wa. Yi o ri wipe ibukun re yi o wa si imuse ninu aye wa, ki o le je ipenija fun awon elomiran lati sin in.
ADURA
Olorun olufe, fun mi ni ore-ofe lati le tele ofin re, fun mi ni ore-ofe lati le fe o ati aladugbo mi, je ki ibukun e kun akunwosile tio fa awon alaigbagbo lati sin o, jowo se eyi ati pupo sii. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
