KRISTI NI ONA SI ODO OLORUN
Paulu salaye iru eni ti Jesu Kristi nse ati agbara nla re ti o wa di ibukun wa. Paulu wipe Eni (Olorun) ti o gba wa kuro lowo agbara okunkun, ti o si si wa nipo sinu ijoba ayanfe Omo re, ninu eni ti awa ni idande nipa eje re, ani idariji ese. Eni tii se aworan Olorun ti a mo ri, akobi gbogbo eda. Nitori ninu re ni a ti da ohun gbogbo, ohun tin be ni orun, ati ohun tin be ni aye, eyi ti a ri, ati eyi ti a ko ri, won iba se ite, tabi oye, tabi ijoba, tabi ola, nipase re ni a ti da ohun gbogbo, ati fun un. Oun si wa saaju ohun gbogbo, ati ninu re ni ohun gbogbo duro sokan. Oun si je ori fun ara, eyi ni ijo, eni tii se ipilese, akobi lati inu oku wa, pe ninu ohun gbogbo ki oun ki o le ni ipo ti o ga ju lo (Kolose 1:13-18)
EKO
Olorun ti a ko le ri, ti fi ohun gbogbo han nipase Omo re Jesu Kristi. O wa rorun fun enikeni lati mo iwa Olorun. Jesu Kristi ni awo digi Olorun, Nipa re gbogbo eniyan ni yio ri idariji ese gba. Nipase Jesu Kristi, gbogbo eniyan lo le de odo Olorun (Jesu Kristi ni, ebun iye ayeraye, fun enikeni ti o ba setan lati gbaa gbo). O se pataki ki gbogbo eniyan ni idapo ti o dara pelu re, ki o si jewo re bi Oluwa ati Olugbala.
ADURA
Jesu Olufe, mo mo o, mo mo titobi re. Iwo ni Kristi, Olugbala gbogbo aye. Mo jewo re ni Oluwa, mo gba o gege bi Olugbala mi. Mo fi gbogbo aye mi fun o, mo se ileri lati sin o titi fun gbogbo aye mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, ki emi le gba ebun ayeraye ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
