JIJE OUNJE TI EMI
Awon ti won je anfani Jesu nipa ipese ounje iyanu, won ko ni arojinle okan. Won ni itumo odi pe Jesu je pidan-pidan. Won si nfe ki o di oba ki o le te won lorun fun opolopo idan. Sugbon Jesu se atunse, o wi fun won pe looto looto ni mo wi fun yin, eyin nwa mi, kii se nitori ti eyin ri ise ami, sugbon nitori eyin je isu akara won-on-ni, eyin si yo, ema se sise fun ounje ti isegbe, sugbon fun ounje to wa titi di iye ainipekun, eyi ti omo-eniyan yoo fifun yin, nitoripe oun ni, ani olorun baba ti fi edidi di.
(Johannu 6:26-27).
EKO
Ounje fun inu, inu fun ounje, gbogbo re ni a o parun papo. Akitiyan eda koni lati duro lori ounje ti ara, ti a o ya sile igbe. Gbogbo eniyan ni lati maa le ounje ti emi ti yio wa titi ayeraye. Jesu Kristi ni ounje iye ti yio wa titi lae. Enikeni ti o ba si je ninu re, ebi ki yio pa mo lae lae. Jesu wipe ‘emi ni ounje iye, enikeni ti o ba to mi wa, ebi ki yoo paa, eni ti o ba si gba mi gbo, orungbe ki yoo gbe mo lae‘ (Johanu 6:35).
ADURA
Jesu Kristi olufe, mo gbagbo pe iwo ni ounje iye ti o ti odo olorun wa, mo si jewo re gege bi oluwa ati olugbala mi. Nitori naa emi yio sin o pelu gbogbo ipa ati agbara mi, emi yi o tele o titi de opin ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
