JI SI IWALAYE IGBE EMI
Awon Farisi je ota alatako Jesu Kristi, won lo esin won gege bi iboju fun owu ati gbigbogun tii. Awon Farisi ko simi lati maa tele Jesu kiri ni gbogbo ojo, lati lee wa esun sii lese nipa ise iranse re. Bibeli salaye die ninu iwa awon Farisi. O si se ni ojo isimi keji leyin ekini Jesu koja laarin oko oka, awon omo ehin re si nya ipe oka, won nfi owo raaje. Awon kan ninu awon Farisi si wi fun won pe, eese ti eyin fin se eyi ti ko ye lati se ni ojo isimi?
Bibeli tun salaye wipe o si se ni ojo isimi miran, ti o wo inu sinagogu lo, o si nkoni, okunrin kan sin be nibe ti owo re otun ro. Ati awon akowe ati awon Farisi n so o, bi yoo mu un larada ni ojo isimi, ki won ki o lee ri ona ati fii sun. (Luku 6:1-2, Luku 6:6-7)
EKO
Satani feran lati mu ki awon asoju ibi re ki o maa so awon omo Olorun lati lee bi won subu, Ilepa ota ni lati maa wa isubu onigbagbo nipa igbe aye otito won yi o maa soro abuku, won o maa soko oro si won pelu ireti wipe okan yi o ba won tabi yori si isubu won. Nitorinaa onigbagbo nilati kun fun adura, ki o si ja fafa ninu emi, ki won si kun fun emi mimo. Onigbagbo nilati mo wipe ete Satani kii se lati mu won rewesi lati sin Olorun nikan, bikose lati jale, ati lati pa, ati lati parun, igbala won. (Johanu 10:10). Bi awa (onigbagbo) se kun fun adura ati sisora, a lee tele apere Jesu ni gbogbo igbese wa. Fun apere nigba ti Satani lo awon Farisi lati gbogun ti Jesu.
Jesu ko awon Farisi – onigbagbo nilati ko awon ajinilese sile. Jesu tesiwaju ninu sise ise Olorun. Ki onigbagbo mase duro lati maa se ife Olorun. Jesu nigba gbogbo maa nlo sibi idake roro lati loo gbadura fun agbara otun. Onigbagbo ni lati maa gbadura fun kikun agbara. Jesu se ayipada ibugbe ki ole bo lowo iyolenu awon ota. Onigbagbo ni lati ni orisirisi eto ninu ise iranse ki ole gbon ju ota re.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni okun lati bori Satani ati yege ni aye yi, fun igbekele oruko re. Bakannaa, fun mi ni okun lati sora fun Esu ati awon asoju ibi re. Je ki Emi Mimo re ro mi ni agbara lati duro sinsin ki emi si maa sin o ni akoko idojuko ati ipenija, Si je ki Emi Mimo re wo mi ni agbara lati maa sora ki nsi maa gbadura, ki emi lee se aseyori ninu gbogbo ise iranse mi, ki imole ihinrere re lee tan kakiri agbaye. Nigba ti ire ije mi ba si dopin, je ki emi wa niwaju re ni orun, ki emi si gbo wipe O ku ise, kaabo iranse mi sinu ayo Oluwa re ni oruko Jesu Krist ni mo beere Amin.
