JESU TI FI IDI IHINRERE MULE
Nikodemu, ijoye nla Farisi, kelekele yo to Jesu Kristi wa ki o le keeko nipa ihinrere ti awon Farisi nse atako. Ni oju atako nigbangba Jesu lo asiko yi lati salaye ihinrere fun Nikodemu. Ibapade yi le tumo si nkan miran fun Nikodemu, sugbon o je anfani fun Jesu lati gba okan la. Mesaya (Olugbala) lo opolopo akoko pelu Nikodemu lati so fun (ati awon elomiran) ohun ti yio na wa lati lee wa ijoba Olorun. Bibeli so nipa iriri Nikodemu pelu Jesu; Okunrin kan si wa ninu awon Farisi, ti a npe ni Nikodemu, ijoye kan ninu awon Juu. Oun naa ni o to Jesu wa ni oru, o si wi fun un pe, Rabbi, awa mo pe olukoni lati odo olorun wa ni iwo ise, nitori pe ko si eni ti o le se ise ami wonyi ti iwo nse, bi ko se pe Olorun wa pelu re. Jesu dahun, o si wi fun un pe, looto, looto ni mo wi fun o, bi ko se pe a tun eniyan bi, oun ko le ri ijoba olorun. Nikodemu wi fun un pe, a o ti se le tun eniyan bi? O ha le wo inu iya re lo nigba keji, ki a si bi? Jesu dahun wipe, looto, looto ni mo wi fun o, bi ko se pe a fi omi ati emi bi eniyan, oun ko le wo ijoba olorun. Eyi ti a bi nipa ti ara, ara ni, eyi ti a bi nipa ti emi, emi ni. Ki enu ki o ma se ya o nitori mo wi fun o pe a ko le se alaitun yin bi. Afefe nfe si ibi ti o gbe wu u, iwo si ngbo iro re, sugbon iwo ko mo ibi ti o ti wa ati ibi ti o gbe nlo, gege bee ni olukuluku eni ti a bi nipa ti emi.
(Johanu 3: 1-8).
EKO
Jesu Kristi lo gbogbo anfani ti o ba ri lati wasu ihinrere fun elese nigba ti o wa ni ile aye. Loju idojuko lati odo awon oninunibini, Jesu koha ti o dara si won. Ko kanra si enikeni, sugbon o tewo gba enikeni ti o ba ni inu didun si ihinrere. Nipa okan pele re si awon Farisi, Jesu dahun gbogbo ibeere Nikodemu. Awon idahun won yi, ti wa di gbongbo igbagbo fun gbogbo kristeni. Won ti wa di eroja, , koko, akori fun Onigbagbo lati lo ni mimu elese wonu igbala olorun.
Jesu wi fun Nikodemu:
-
Looto, looto ni mo wi fun o, bi ko se pe a tun eniyan bi, oun ko le ri ijoba olorun. (Johanu 3:3).
-
Bi mose ti gbe ejo soke ni aginju, gege bee ni a ko le se alaigbe omo-eniyan soke pelu (Johanu 3:14).
-
Nitori olorun fe araye to bee ge, ti o fi omo bibi re kansoso funni ki enikeni ti o ba gbaa gbo ma baa segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun. (Johanu 3:16).
-
Nitori olorun ko ran omo re si aye lati da araye lejo, sugbon ki a le ti ipase re gba araye la. (Johanu 3:17).
-
Eni ti o ba gbaa gbo, a ko ni daalejo, sugbon a ti da eni ti ko gbaa gbo lejo na, nitori ti ko gba oruko omo bibi kansoso ti olorun gbo.
ADURA
Jesu Kristi olufe, iru Oluwa iyanu wo ni o, o ti salaye ihinrere ki gbogbo eniyan le je anfani re. O farada inunibini, o si fi okan ife han larin awon alatako. O jiya orisirisi eebu fun gbigba araye la.Mo feran re Jesu Kristi, mo si gba o gege bi Oluwa ati Olugbala mi, mo jewo pe omo olorun ni o. Mo jewo ese mi, mo si ronupiwada won, emi yi o sin o ni gbogbo aye mi. Mo nlo akoko yi beere ore ofe lati wasu ihinrere, ki awon to gboo le yonda igbe aye won fun o, ni Oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
