OLORUN YIO JA FUN WA
Oba Saulu gbe igbese odi nigbati o gbiyanju lati pa Dafidi, o wa bo si owo Dafidi. Dafidi saanu fun ota re, o si je ko lo lai fara pa. Bibeli salaye idi ti Dafidi se je ki oba saulu lo lai fara pa. Dafidi ti so fun awon eniyan re oun si wi fun awon omokunrin re pe, eewo ni fun mi lati odo oluwa mi, eni ti a ti fi ami-ororo oluwa yan, lati nawo mi sii, nitori pe eni ami-ororo oluwa ni
(Isamueli 24:6).
EKO
Awa omo olorun ni lati mo pe, ogun wa, ogun olorun ni, ki a si je ki o ja fun wa. Ko mu opolo wa, ki a maa ja ogun ti olorun nife lati ja fun wa. A ni lati je ki o ja fun wa dipo ki a ma fi agbara wa sofo. Awon omo olorun ni lati fija fun olorun ja. Ti inu ba bi olorun si awon ota wa, won wo wahala. Olorun ko ni dawo duro ogun ti o ba bere, ayafi ti o ba pari re, yio si ri pe iru ogun bee ko ni yoju mo. Pelu olorun ninu ise, a ko ni laagun, tabi lami loju, a ko si ni dara wa lebi nitori idi kan.
ADURA
Olorun olufe, jowo ja fun mi, ma se je ki ota bori mi, damu won, foro emi won ki won mase bori mi. Ma se je ki nse ife inu mi ti o le faye gba idojuko ota. Je ki nle maa sogo ninu re ninu ohun gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
