OLORUN YIO DARIJI ENIKENI TI O RONUPIWADA
Olorun ni akosile ese awon Israeli, o si siro re fun ijiya won. Niwon bi won ko ti ni iberu Olorun, ti won si nhuwa buburu si ara won, Olorun seleri ijiya to buru fun won. Olorun wipe, ‘Bayii ni Oluwa wi, nitori irekoja meta ti Juda ati nitori merin, emi ki yoo yi iya re kuro, nitori won ti ko gbogbo igbekun ni igbekun lo, lati fi won le Edomu lowo (Amosi 2:6)
EKO
Olorun ni akosile ese, alaironupiwada elese kan ko ni lo lai jiya. Eleda ti o mo ohun gbogbo yio san esan ohun gbogbo. Yi o bukun awon ti o nberu Olorun, yi o fiya je awon olokan lile ati awon ika eniyan. Ohunkohun ko ni koja niwaju Olorun ti o nri ohun gbogbo lai gba idajo to to. Jehofa fe lati bukun elese ju ki o fiya je won. Yi o dari ji elese ti o ba ronupiwa ese re. Enikeni ti o ba beere fun idariji Olorun yi o rii gba. Ni afikun, aanu Olorun lori elese ni odiwon. Ko ni duro laelae fun elese lati ronupiwada. Yi o pala lati se idajo, yi o si ko gbogbo elese ti ko ronupiwada lo si orun ina apadi.
ADURA
Olorun Olufe, jowo fun mi ni agbara lati le bori idanwo ese. Je ki emi mo ese mi, ki emi si ronupiwada won. Je kin ni ore-ofe lati wa ni irele, kin le ri aanu ati ore-ofe gba ni akoko aini mi. Je ki ayo igbala mi wa titi aye mi, si je ki nwo orun-rere, nigba ti mo ba pari ire ije ni aye yi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
