JESU NI OLORUN
Iwalaye Jesu Kristi ko sese bere ni ibujeran nigba ti Maria bii saye, o ti wa latetekose saaju akoko yi. Jesu Kristi ti wa saaju akoko dida aye, o rii o si kopa ninu dida aye, Jesu Kristi lo wa lehin dida aye oun ni oro Olorun ti a fi da ohun gbogbo. Bibeli wipe ‘Ni atetekose ni oro wa, oro si wa pelu Olorun, Olorun si ni oro naa. Oun naa ni o wa ni atetekose pelu Olorun, nipase re ni a ti da ohun gbogbo leyin re a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. Ninu re ni iye wa, iye naa si ni imole araye. imole naa si nmole ninu okunkun, okunkun naa ko si le bori re.
(Johanu kini 1:1-5)
EKO
Igbe aye Jesu Kristi ko bere ni ibujeran nigba ti Maria bii, Jesu Kristi ti wa saaju akoko majemu titun, Jesu Kristi ti wa pelu Olorun ni orun saaju akoko dida aye. Jesu Kristi ko see ya kuro lara Olorun oun ni imisi Olorun, oun si ni ohun Olorun, Jesu ni ohun ti Olorun lo lati da aye ati ohun gbogbo ti o wa ninu re. Awon eniyan le pe Jesu ni omo Olorun, ko se ya kuro lara Olorun onakansoso ti a nfe lati ya Jesu ninu Olorun jasi yiya Olorun ati ohun re, nitorina bi a ko se le ya Jesu Kristi lara Olorun a le so pelu igboya pe Jesu Kristi je Olorun. O je Olorun ninu eniyan.
ADURA
Jesu Kristi olufe, mo gba o gbo gegebi Olorun ninu eniyan, niwon bi mo se mo o gege bi omo Olorun mo ni igboya lati pe o ni Olorun. Mo ni imoye pe ohun amuye lati lo si orun ni lati gbagbo pe omo Olorun ni o, won si ni lati jewo re ni Oluwa (Johanu 3:16, Romu 10:9) nitorina mo setan lati le kun oju osuwon, mo jewo Jesu Kristi ni omo Olorun (Olorun ninu eran ara) mo si gba o ni Oluwa ati olugbala mi. Amin.
