JESU; EMMANUELI ILERI
Olọrun fi han woli Isaiah onạ abayọ patapata si rogbodiyan aye. Bi awọn eniyan ko ṣe ni imọ ṣọkan nipa ofin Olọrun, woli Isaiah jẹ ko ye wọn ilana Olọrun ti o wipe
‘Nitorina Oluwa funra rẹ yio fun yin ni ami kan, kiye sii wundia kan yoo loyun, yio si bi omọkunrin kan, yi o si pe oruko re ni Immanueli’. (Isaiah 7:14).
ÈKỌ́
Jesu Kristi ni Immanueli ti a o bi gẹgẹ bi asọtẹlẹ Isaiah (Isaiah 7:14). Nitotọ a bi Kristi, o si pese ona abayọ si ruke rudo tabi aini ifọkanbale agbaye. Nipasẹ iku ati ajinde Jesu, gbogbo ibeere aye ni a ri idahun si. Gbogbo eni ti o kepe Orukọ rẹ ti o si gbaa gbọ yio ri ẹbun iye ayeraye gba. Ẹnikeni ti o ba jẹwọ Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala yio jogun iye ayeraye ni Ọrun.
ADURA
Olọrun, mo gbagbọ pe Jesu Kristi kan sọsọ ni Ọmọ rẹ ti a ran lati gba araye la. Nipasẹ rẹ, mo ri igbala ati ẹbun iye ayeraye Nigba ti ko si orukọ miran labẹ Ọrun ti a fi le ri igbala. Mo jẹwọ ijolotitọ fun Jesu Kristi, mo si ti pinu lati sin ni gbogbo iyoku aye mi. ki Olọrun ran mi lọwọ. Amin.
