JE ONIRELE NIWAJU OLUWA
Gbogbo eniyan je nkan, bi kose bi amo lowo amokoko. Olorun ni amokoko, awa ni amo. O ni gbogbo agbara lori wa oun ni o da gbogbo agbaye, ohun gbogbo si nteri ba fun un. Olorun so ninu Bibeli pe, Eyin ile Israeli, emi ko ha le fi yin se gegebi amokoko yi ti se, ni Oluwa wi, sa woo, gege bi amo ni owo amokoko, bee ni eyin wa ni owo mi, ile Israeli (Jeremiah 18:6)
EKO
Awa eniyan ko ni ohun gbogbo, sugbon Olorun ni ohun gbogbo. Laisi re, a ko le wa, o si ni gbogbo ase ati agbara lori wa. A ko gba wa laye lati se ohun ti o ba wu wa, ayafi bi won ba te Eledaa lorun. Ki a bu ola fun un, ki a si gboran si ofin re, ki a le se rere.
ADURA
Olorun Olufe, se mi ni onirele niwaju re, ki emi si bola fun o pelu iberu. Mase je ki njora mi loju, ki emi wa se arifin re (ailee bowo fun o). Niwon bi iwo ti je amokoko ti emi si je amo, je ki emi gba imoran re, ki e mi le se aseyori ni gbogbo ona mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
