IWA ELETAN NI ATUNBOTAN
Ile aye yi fun igba die ni, gbogbo ohun tin be nile aye fun igba die ni. Gbogbo oro aye yi yio dibaje, won o si parun laipe, ologbon oniwaasu ninu Bibeli wipe ‘Mo ti ri ise gbogbo ti a nse labe oorun, si kiye sii asan ni gbogbo re ati imulemofo. (Oniwaasu 1:14).
EKO
Aye ti eniyan wa yi fun igba die ni yi o wa, gbogbo oro ti eniyan nkojo ni yio dibaje, won ko ni wa titi lae lae. Olorun yio da aye titun ati orun titun fun awon eniyan mimo re, ti yio wa titi ayeraye. (Ifihan 21:1-4) ewa ati oro Olorun ni paradise titun yi o wa titi lae lae, Olorun ko ni le je ki elese ti ko ronupiwada wo inu ijoba re ti o rewa. Yi o ran won lo si orun ina apadi ti yio wa titi lae, ti a seto fun Satani ati awon omo ehin re (Matiu 25:41) (Enikeni ti o ba gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala, ti o ronupiwada kuro ninu ese re ni a npe ni eniyan mimo Olorun, won yio lo si orun rere).
ADURA
Olorun olufe, mo mo pe aye yi ati ohun gbogbo ti nbe ninu re jasi asan, won je idibaje won o si parun ni ojo kan. Mo setan lati to oro mi jo sibi ti ko ni baje, mo pinu lati fi aye mi fun Jesu Kristi looni, emi (daruko ara re) jewo igbagbo mi ‘mo Gbagbo pe Jesu Kristi je omo Olorun, o ku fun ese mi ki emi lee ni iye ayeraye. Mo jewo ese mi (so awon ese ti o le ranti) mo si jewo awon ese ti emi ko lee ranti, mo ronupiwada gbogbo ese mi, mo si fi gbogbo aye mi fun Jesu Kristi ni otito, emi yio sin-in fun gbogbo ojo aye mi. Bi mo si ti di omo Olorun, emi yi o rohin iriri igbala mi pelu eniyan gbogbo, ki Olorun ki o ran mi lowo. Amin.
