ISOKAN AWA KRISTENI
Kristieni ni lati mo Pataki wiwa ni isokan, ki a si wa ni isokan pelu ara wa. Bibeli ni ki a yeara fun ipinya ati owu ti o le je idiwo fun wiwasu ihinrere, ko si kristieni ti o ni lati je gaba lori awon ti o ku unse lo ye ki a wa ni irele ninu emi ki a si se aponle awon ti o ba ku. Bibeli wipe ‘Eni ti o ba nkiyesi ojo o nkiyesi fun Oluwa, eni ti ko ba si kiyesi ojo fun Oluwa ni ko kiyesi. Eni ti njeun o njeun fun Oluwa nitori o ndupe lowo Olorun, nitori ko si enikan ninu wa ti o wa laaye fun ara re, ko si eni ti o ku fun ara re. nitori bi a ba wa laaye awa wa laaye fun Oluwa, bi a ba si ku awa ku fun Oluwa nitori naa bi a wa laaye tabi bi a ku ni ti Oluwa ni awa se.
(Romu 14:6-8)
EKO
Isokan yi o fa itesiwaju awa kristieni sugbon ipinya yi o fa idiwo itankale ihinrere, o se ni laanu pe Satani ti tan kristieni je ti a wa unfi igberaga je ara wa lese. Elesin jesin ati ilepa ohun ofo aye yi ti ko mu ohun rere kan wa si ijoba Olorun. Olorun unfe ki awon omo re maa sin in ninu iwa mimo ati ominira emi, lai wonu ariyan-jiyan pelu ilara. Gegebi (Romu 14:6-8) Olorun faye gba ijosin otito ati ominira emi, bi enikeni ba fara mo ofin Mose lati maa josin ni ojo abameta (Satide) je ki o se bee. Bi o ba ko lati je eran eleda mase kegan re, bakan naa eni to fe ma je ewebe tabi eso pelu ise iranse kristieni re, ko dese Olorun ko so wipe asa ibile wa ni yio sise igbala wa. Ile aye yi ni eyi mo igbala nipase Jesu Kristi ni ona kan soso ti Olorun seto ona ti o lo sorun, enikeni ti o ba gbagbo ninu Jesu Kristi yi o di eni igbala bi o ti wu ki asa tabi igbe aye re se ri tele.
ADURA
Olorun olufe jowo gba awujo kristieni ninu ajakale aisokan ati ipinya, je ki awa olufe siwo dida ara wa lebi tabi wiwa esun si ara wa lese. Je ki a le dojuko bi wiwasu ihinrere yi o se ma dagba sii, je ki ijo kokan le fara da fun ra won ni isokan ki a le segun awon ota ihinrere. Je ki ijo Olorun ki won lo oro ati agbara won fun tesiwaju ihinrere ti i o mu ki awon alaigbagbo le ronupiwada ki won si di kristieni. Jowo ro ara kristieni ni agbara jake jado agbaye ki a le lepa ododo, ki oruko re le di yinyin ni ile alaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
