ISESI ONIGBAGBO
Arabinrin kan ti a unpe ni Febe ni Paulu se akiyesi itara re fun ise atokanwa re. Paulu se akiyesi igbiyanju re lati ran awon eniyan lowo, Paulu so ninu akosile re wipe ‘Mo fi Febe arabinrin wa le yin lowo eni tii se diakoni ijo ti o wa ni Kenkrea. Ki eyin le gbaa ninu Oluwa bi o ti ye fun awon eniyan mimo, ki eyin ki o si ran lowo isekise ti o n wa ni iranlowo lodo yin, nitori oun pelu ti unse oluranlowo fun eni pupo ati fun emi naa pelu.
(Romu 16:1-2)
EKO
Ise iranse wa gege bi kristieni ko pin si ijosin ni ojo isinmi (AIKU) nikan, a ni lati fi ife Kristi han ninu ati lehin ijosin. O se Pataki ki a waasu ki a si pese fun aini awon eniyan, opolopo kristieni ni won nilo awon ohun ti a ko le lo mo, awon kan ko fe ohun ini sugbon won fe idapo. Onigbagbo ni lati se akiyesi aini awon to yi waka ki won si gbiyanju lati pese fun won, boya yi o na wa ni owo tabi ohun ini tabi beeko, awa ara ni lati wa ni isokan ki a si se ohun gbobgo pelu ife gege bi Kristi se unreti. A ko ni lati yo arakunrin tabi arabinrin kan sile lai ba aini re pade, kristieni kookan je ara ijoba Olorun, ki a fi owo ba ara wa lo niwon bi o ti je pe alajopin ni wa ninu anfani Olorun. O ni lati maa gbin ni okan wape Olorun nwo isesi wa si arakunrin wa, ohunkohun ti a ba unse si arakunrin ati si arabinrin wa, Olorun ni a unse si, Olorun unwo wa.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo gege bi kristieni lati sa gbogbo ipa mi lati le ran awon ara lowo lona ti o ye. Jowo je kin wulo ninu ijoba re, mo fe sin o lotito kin si ran awon eniyan lowo, pese fun mi ki nbaa le ran arakunrin ati arabinrin lowo, wo mi ni agbara lati le duro kin si ti ihinrere lehin ati awon ti o sunmo mi. Fun mi ni imo ati agbara lati le se ohun kohun ti yi o polongo oruko re sinu aye awon elomiran, ki oruko re je gbigbega ni gbogbo akoko, lehin ohun gbogbo je kin gbo ohun pe O ku ise, kaabo ojise mi daradarani orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
