ILE AYE KUN FUN IKA
Judasi Iskarioti, ti o je okan lara awon omo ehin Jesu Kristi gba abetele, o si fa oga re le awon ota lowo. Bibeli wipe satani si wo inu Judasi, ti a npe ni Iskariotu, okan ninu awon mejila. O si mu ona re pon, o lo lati ba awon olori alufaa ati awon olori eso gbi mo on po,bi oun iba ti fi le won lowo. Won si yo, won si baa da majemu ati fun un ni owo. O si gba, o si nwa akoko ti o lo lati fi le won lowo laisi ariwo.
(Luku 22:3-6).
EKO
Ise iyanu ko ni dopin ni aye. Ile aye kun fun ika, awon ohun ti o koja ero eniyan nsele. Nile aye yi, omo odo nda oga re, ebi npinya, won ko le fokan tan ara won. Aye ti o si kun fun orisirisi ise ibi ko ni wa titi lae. Opin yi o de ba aye yi lojo kan, aye ti o pe ni olorun yi o fi ropo re. Olorun yio pa run gbogbo eniyan buburu ti o ti gbe ninu aye buburu yi. Yi o ko awon olotito lo sinu aye pipe ti yi o da.
A ro gbogbo eniyan ki won se ara won ni pipe ki won le bo kuro ninu aye buburu yi, ki won le ni ipin ninu aye pipe ti nbo.
ADURA
Olorun olufe, mo nimo pe aye isinsinyi kun fun ibi ati pe iwo yi o paa run laipe, iwo yi o da aye titun fun awon eniyan mimo re. Mo fe ye fun aye titun ti nbo. Jowo ka mi ye, ran mi lowo lati ma se ikiyesara awon amuye ki nle yege. Jowo je ki igbagbo mi ninu omo re Jesu Kristi ka mi ye fun ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
