IGBORAN SAN JU EBO LO
Oba Saulu se asilo ibasepo re pelu Olorun, o si se opolopo asise eyi ti iba tele ilana Olorun ki o gba ibukun, Saulu yan lati te ara re lorun, o saigboran si Olorun. Ijakule Saulu fara han nigba ti o kuna lati pa gbogbo ota Olorun re patapata, ofin na so wipe Samueli si wi fun Saulu pe Oluwa ran mi lati fi ami ororo yan o ni Oba lori eniyan re, lori Isreali nitori naa nisisiyi iwo feti si ohun oro Oluwa. Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi, emi ranti eyi ti Amaleki ti se si Isreali, bi o ti lumo de e ni ona, nigba ti oun goke ni Egipti jade wa. Lo nisisinyi ki o si kolu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan won ni aparun, ma si se da won si sugbon pa ati okunrin ati obirin won, omo kekere ati ti o wa ni enu omu, maalu ati agutan, ibakasi ati ketekete. Saulu se aigboran si ofin Olorun
(Samueli kinni 15:1-3). O pa die ninu awon ota Olorun, o si da awon oro ile naa si fun ilo oro tire. O si se awawi pe oun fe fi ohun ti oun dasi se irubo si Olorun. Wolii Samueli ba Saulu oba wii ‘Oluwa ha ni inu didun si ore sisun ati ebo bi ki agba ohun Oluwa gbo, kiyesii igboran san ju ebo lo, ifetisile si san ju ora agbo lo (Samueli kini 15:22) niwon bi Saulu oba ti ko lati tele ase Olorun, a koo sile gegebi oba Isreali, a si yan Dafidi ni oba sipo re.
EKO
kiyesii igboran san ju ebo lo, ifetisile si san ju ora agbo lo (Samueli kini 15:22) Igboran ko ni eda, Olorun unfe ki agboran si ase re, ohunkohun ibaa maa na wa, a ko ni lati se ife ti ara wa ki asi fe ki Olorun gba fun wa, a nilati se ohun ti o ba feki a se, a si ni lati se daradara. Bi o se ti Olorun a nilati se ife re ki a to se awawi. Olorun yi o bukun awon omo re ti o ba gboran. Yi o bu ola fun enikeni ti o ba pa ofin re mo. Olorun le se ayipada ofin fun idi lati bukun ati bu ola fun enikeni ti o ba beru ti o si pa ofin re mo, nitori na a ro gbogbo eniyan lati gboran si ofin Olorun niwon igbati won ko ni kaabamo ise won.
ADURA
Olorun olufe mo mope o fe ki gbogbo eniyan fi otito gboran si ofin re, ki won si tele ilana re. nitorina mo setan lati younda aye mi ati lati gboran si gbogbo ofin re, emi yi o sin o un o sibu ola fun o niwon igba ti moba wa laaye. Mo unlo akoko yi lati beere fun opo ore-ofe ti yi o mumi te o lorun ni gbogbo igba. Fun mi ni ore-ofe ki unle di eni ibukun ni aye yi ati ni orun rere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
