ELERU NIYIN NI OLUWA
A mo Olorun nipa sise idajo otito, a yin oruko re nipa didara re si eda eniyan. Bibeli wipe Oluwa joba, ki a ye ki o yo, je ki inu opolopo erekusu ki o dun . Awosanma ati okukun yii ka, ododo ati idajo ni bujokoo ite re. Ina saaju re, o si jo awon ota re yikakiiri. Manamana re ko imole si aye, aye ri i, o si wariri. Awon oke nyo bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aye. Orun fi ododo re han, gbogbo Orile-Ede si ri ogo re. (Orin Dafidi 97:1-6)
EKO
O ye ki awa Kristeni maa yin Olorun ni gbogbo igba fun didara re ninu aye wa. Ti a ba ka oore re, a o rii pe Eledaa ti se opolopo ise iyanu ninu aye wa ati awon eniyan wa. Iyanu Olorun ko lopin, yio tun se opolopo ise iyanu bi a ba tesiwaju lati maa yin in, ki a si gbeke lee.
ADURA
Olorun Olufe, je ki enu mi kun fun iyin re, fun mi ni okun lati le maa ka ibukun re ninu aye mi, je kii eri mi je ohun ti yio mu mi sin O sii. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
