EJE JESU DOJUKO O SI BORI GBOGBO EJE OMIRAN
Iyato nla wa laarin ise Alufaa ti majemu laelae ati ti akoko Jesu Kristi. Alufaa ti majemu laelae ni lati maa fi eranko se irubo fun ese eniyan nigba de igba, sugbon Jesu fi ara re se irubo leekan fun gbogbo eniyan. Bbeli salaye wipe “Nitori ko see se fun eje ako maaluu ati ti ewure lati mu ese kuro. A si tun koo pe, sugbon oun leyin igba ti o ti ru ebo kan fun ese titi lae, o jokoo ni owo otun Olorun, lati igba naa lo, o nreti titi a o fi awon ota re se apoti itise re. Nitori nipa ebo kan, o ti mu awon ti a so di mimo pe titi lae. (Heberu 10:12 -14).
EKO
Jesu Kristi gba eniyan sile nipa irubo igba gbogbo, ti o so eniyan si irubo ti ko pa ese re patapata. Omo Olorun fi aye re so irubo, ti o pa ese eniyan re patapata, o si mu won pada si odo Olorun. (Lati ehin wa, awon Alufaa nfi ewure ati aguntan se etutu ese eniyan, sugbon gbogbo eyi ko mu asepe wa, niwon bi eje eranko ko le pa ese re, Eje Jesu ti o kun fun Emi, ni a lo lati pa ese eniyan re fun irapada ayeraye. Gbogbo awon eniyan ti won gbekele Jesu Kristi, ti won si ti gbaa ni Oluwa ati Olugbala won, ko ni fi eranko se irubo mo, Jesu ti fi Emi re se irubo fun wa. Enikeni ti o ba jewo Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala re yio ri idariji ese gba, a o si ko oruko re sinu iwe iye.
ADURA
Eyin Olorun logo, Jesu Kristi ti fi emi re se irubo fun ese mi. Omo Olorun ti yowo fifi ewure ati aguntan se irubo ese mi. Bi mo se je onigbagbo ninu Jesu Kristi, a ti we ese mi nu, ade ododo nduro de mi ni orun-rere. E yin Olorun logo, a ti ko oruko mi sinu iwe iye. Mo je omo Olorun, orun si ni ile mi. O seun Jesu Kristi, fun gbigba okan mi la. Ero okan mi ni lati sin o ni gbogbo aye mi, eyi ni emi yio se nigba ti ore-ofe re yio wa lori mi, Olorun ran mi lowo. Amin
