DURO SINSIN PELU JESU
Aposteli Paulu re awon eniyan mimo ni Filippi o wipe kiki ki e saa je ki iwa-aye yin ki o maa ri gege bi ihinree Kristi, pe yala bi mo tile wa wo yin, tabi emi ko si, ki emi ki o le maa gburoo bi e tin se, pe eyin duro sinsin ninu Emi kan, eyin jumo njijakadi nitori igbagbo ihinrere, pelu okan kan. Ki e ma si je ki awon ota deru ba yin ni ohunkohun, eyi ti se ami ti o daju fun iparun won, sugbon ti igbala yin, ati eyini ni lati owo Olorun wa. (Filippi 1: 27-28)
EKO
Oje ohun ti o ye, ohun to dara ki a mu iduro wa daadaa ninu Jesu Kristi. Inilara ati inunubini yio dide si awon eniyan mimo sugbon onigbagbo ni lati farada gbogbo won. Olorun ni esan nla fun awon ti ntele Jesu Kristi ti o ko lati teriba si inunibini, yio san ere iduro sinsin wa pelu ade ogo re ni orun. Eyi nikan ko, Olorun yio mu ki ise wa ni aye duro titi. Awon ise rere yio wa titi lehin ti a ba fi aye yi sile lo si orun. Olorun yio maa se itoka si ise wa ti o dara, yio si bukun awon iran ti o ba ntele wa.
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni Kristeni ti o mu iduro re sin sin ti ko ni kuna igbagbo nitori inunibini. Ran mi lowo lati duro, ki nsi fi otito sin o titi de opin. Jowo bukun mi ati ebi mi, ki gbogbo awon ti o ba tele o ni otito gba ade ogo ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
