AWON ONIGBAGBO GBODO TO IPA JESU FUN ASEYEGE NI ISE IRANSE
Jesu Kristi ji oku Omode dide, o si faa le iya re lowo ti o ro wipe ireti re kan soso ti tan. Bibeli rohin pe ‘ Bi o si ti sunmo enu-bode ilu naa, si kiyesii won ngbe oku kan jade. Omo kan soso naa ti iya re, o si je opo, opoijo eniyan ilu naa si wa pelu re. nigba ti Oluwa si rii, aanu re see, o si wi fun un pe ma sunkun mo. O si wa, o si fi owo to aga posi naa, awon ti si nru duro je, o si wipe Odomokunrin, mo wi fun o dide. Eni ti o ku naa si dide jokoo, o bere sini fohun, o si faa le iya re lowo (Luku 7: 12-15).
EKO
Jesu Kristi ni ipinu pataki lati ma wasu ihin-rere ijoba Olorun ni igba aye re. o rin lori ile ati lori okun fun sise ise yi. Sugbon kii se pe omo olorun ni ife lati ma wasu ijoba olorun nikan, o tun nsanu eniyan ni gbogbo ibi to ba lo. Jesu ma nwa nigbangba lati ma se ipese fun awon eniyan nipa ti ara ati nipa ti emi. Fun apere, pelu iyanu o bo egberun eniyan pelu isu akara marun ati eja meji nigba ti o ri pe ebi npa won (Luku 9:16). O si tun ji oku omo kan dide nigba ti o ri iporuru okan iya re (Luku7:12-15) bakan naa, awa Kristieni ni lati ma se be ki ama saanu fun awon ti o ba yi wa ka. Ki ise ipolongo ihinrere le pe, anilati gbiyanju lati bo awon ti ebi npa, alaini, bo ihoho won, ki a be awon alaisan wo. Ojuse wa si ni lati ma gbadura fun awon ti o ni idojuko nipa idanwo tabi igbagbo won. Niwon igba ti a ba nsanu fun awon eniyan, imole ihinrere yi o tan yi agbegbe wa ati si ona jinjin. Opolopo yi o fe wa ni imo nipa Jesu Kristi won a si di eni igbala.
ADURA
Jesu Kristi, jowo ran mi lowo lati le saanu fun awon eniyan. Fun mi ni agbara ati okan ife ti yio ma fa awon eniyan lati sin o nipa fifi ife otito han won. Je ki ore-ofe re ati ewa didara re san yi mi ka, ki o si ran mi lowo lati ma tan ina ihinrere. Jowo ro mi lagbara lati le je asoju re toto ni aye, ki nsi se itewogba ninu ijoba re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
