AWON OLODOODO YIO JE ALABUKUNFUN
Ileri Olorun daju lori enikeni ti o ba fi otito sin in. Bibeli fi idi eyi mule nigba ti O wipe Olododo yio dagba bi igi ope, yio dagba bi igi kedari Labanoni. Awon eni ti a gbin ni ile Oluwa yio dagba ni agbala Olorun wa. Won o maa so eso sibe ninu ogba won, won o sanra, won o maa tutu nini. (Orin Dafidi 92:12-14)
EKO
Enikeni ti o ba nsi Olorun ni otito ko ni padanu ohun kohun, sugbon yio jere ohun gbogbo fun ara re. bi a ba se nsin Olorun sii ni yio maa dara fun igbe aye wasi. Eledaa yio silekun opolopo anfani fun wa, yio si rojo ibukun re sori wa. Awon alaigbagbo yio ri ibukun wa, yio si fa won lati sin Olorun wa.
ADURA
Olorun Olufe, fun mi ni ore-ofe lati sin o ni otito ni gbogbo igba, ki emi le ye fun ibukn re. Polongo ibukun re ninu aye mi ki gbogbo eniyan le jeri si didara re ninu aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
