ASEYORI NBE LODO OLORUN
Solomoni ko tempili tuntun, o si fi fun Olorun. O si ko awon eniyan re jo, o gbadura fun won. A koo wipe ‘O si se bi Solomoni ti pari gbigba gbogbo adura ati ebe yi si Oluwa, o dide kuro lori ikunle ni eekun re niwaju pepe Oluwa pelu tite owo re si oke orun. O si dide duro, o si fi ohun rara sure fun gbogbo eniyan Isreali wipe, ibukun ni fun Oluwa ti o ti fi isinmi fun Isreali eniyan re, gege bi gbogbo eyi ti o ti se ileri, ko seku oro kan ninu gbogbo ileri rere re ti o ti se lati owo Mose iranse re wa.
Oluwa Olorun wa ki o wa pelu wa bi o ti wa pelu awon baba wa, ki o ma fi wa sile, ki o ma si se ko wa sile. (Awon Oba Kini 8:54-57)
EKO
Olorun ni agbara lati ran enikeni lowo lati se aseyori. Yi o se atilehin eni ti o ba nlepa nkan kan pelu ero rere, Eleda yi o lo ipa ra lati se iranlowo nla fun eni ti o ba nlepa idokowo nla pelu iberu Oluwa. Ko ni si kosese fun iru eni bee sugbon eni ti ko ba ni ero rere, ko lee ni aseyori. Bi o tile ni aseyori ko lee pe, aseyori ti yi o pe ti awon elomiran tun le jogun ni lati wa pelu iberu Olorun.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo kin le ni ero rere, ki emi lepa ohun ti yi o ri ibukun re gba. Je ki ero ati ihuwasi mi ki o je eyi ti o se awon eniyan ni anfani, si je ki igbiyanju mi yin oruko re, mu mi se aseyori ninu idawole mi gbogbo, ki emi si je eni ti yi o pin eri didara re jakejado gbogbo agbaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
