ASE ISE IRANSE
A gba Kristeni niyanju ki won mase doju ko ipenija ti won ba ni, sugbon ki won dojuko Olorun. A le fara jo Jesu Kristi ki a se bi o ti se si awon ipenija ti o ni nile aye. Jesu Kristi gbe oju re si Olorun, o si se aseyori ise irapada, Bibeli wipe ‘Nitori naa, bi a ti fi awosanmo ti o kun to bayi fun awon elerii, yi wa ka, eje ki a pa ohun idiwo gbogbo ti si apa kan, ati ese ti o rorun lati di mo wa, ki a si maa fi suuru sure ije ti a gbe ka iwaju wa. Ki a maa wo Jesu Olupilese ati alasepe igbagbo wa, eni nitori ayo ti a gbe ka iwaju re, ti o fara da agbelebuu laika itiju si, ti o si jokoo ni owo otun ite Olorun. (Heberu 12:1-2).
EKO
Kristeni ni lati sa ere-ije ti Emi pelu ikiyesara ki won ba lee pari re dara dara. A ko gbodo fi aye gba ohunkohun laye lati gba wa kuro ninu irin ajo wa si orun. A ni lati sin Olorun ni otito, ki a jewo ese wa, ki a si ronupiwada won patapata. Kristeni ti nlepa orun-rere ni lati bori idanwo, ki o si duro ninu otito. Kristeni Atunbi tooto ni lati maa sin Olorun ni ojoojumo, ki o si maa polongo ihinrere bi o ba se nipa to. Kristeni ni lati kun fun emi mimo, kun fun adura gbigba, ati yin yin Olorun ninu ewa iwa mimo. Ere Olorun nbe lorun fun awon ti o baansin-in ti a si ruu lokan soke. Awon ti o ba simi le Olorun-Eleda yio gbadun ifokanbale ati ibukun ni orun.
ADURA
Jerusalemi ti orun, orin mi ati ilu mi, ile mi nigba ti mo ba ku ayo ibugbe mi. Nibi ayo, nigba wo ni emi o ri oju re Olorun mi, pelu re, lati ri oju re. Olorun Olufe, mo fe lo si orun, emi ko fe ki ohunkohun dena mi lati wonu ijoba re. Jowo ko mi bi mo se le je omo kin le sin o pelu igbekele. Fun mi ni ore-ofe lati mu iduro mi sin sin, ninu idapo pelu re. Mase je ki emi subu sinu idanwo ati pakute. Ran mi lowo lati sin o ninu ewa iwa mimo; ki ijosin mi si je itewogba niwaju re. Jowo bukun fun mi ni ile aye ati eyi ti nbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
