AKO GBODO GBESAN
Okunrin olojukokoro kan ti o fe gba ore puro fun Dafidi pe oun ni o pa Saulu Oba (Ota re), sugbon Dafidi doju tii dipo ore Dafidi se iwadii won si fi iya arufin je e. Dafidi kigbe o si sokun fun oba Saulu, o si ni ki awon ore re se bee. Dafidi so nipa oriki oba Saulu, o wipe ‘Ewa re Isreali ni a pa ni oke giga re, wo bi awon alagbara ti subu, e ma se so o ni Gati, e ma si se kokiki re ni igboro Askeloni, ki awon omobirin Filistini ki o ma baa yo, ki omokunrin awon alaikola ki o ma baa yo. Eyin oke Gilboa, ki iri ki o ma se ati ki ojo ki o ma ro si yin, ki e ma si ni oko ore ebo nitori nibe ni a gbe so asa awon alagbara nu, asa Saulu bi eni pe a ko fi ororo yan an.
(Samueli keji 1:19-21)
EKO
Gbogbo eniyan ni lati siwo gbigbesan nitori esan gbigba je ti Olorun, a le maa jijakadi lati dariji, Olorun nfe ki a dariji awon ti o ba se wa. O se Pataki ki a keko lara Jesu Kristi ti o ngbadura fun awon ota re titi de oju iku. Olorun mo bi yi o ti se idajo lai si ki a da sii, o si ye ki a je ki o se bo ti wuu. Eyi ti a o fi fe gbesan, ona iwosan pipe lo ye ko je wa logun. A unreti wa ki a gbadura ki Olorun wo wa san ninu irora ati ipalara ti a nje irora re. olorun yi o wo gbogbo ogbe wa, yi o si se idapada awon ohun ti a sonu.
ADURA
Olorun olufe mo beere ki o fun mi ni ore-ofe lati le dariji gbogbo eniyan ti o se mi, ro mi ni agbara lati le dariji bi ko tile rorun fun mi, mase je kin se idajo sugbon ki nfa ohun gbogbo lewo idajo re, ni ona ti yi o yin oruko re, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
