AGBODO DURO SINSIN
Onidajo pilatu wo ariyanjiyan awon farisi nipa Jesu, ko si ri idi otito kan lati daa lejo iku. Pilatu ba awon olori alufaa soro, o si so fun won wipe, eyin mu okunrin yi to mi wa bi eni ti o npa awon eniyan ni okan da, si kiyesii, emi waadi ejo re niwaju yin, emi ko si ri ese lowo okunrin yi, ni gbogbo nkan wonyi ti eyin fi sun si ati herodu pelu, o si ran pada to wa , si kiyesii, ohun ko ye si iku a ko se sii ti owo re wa.
(Luku 23: 14-15).
EKO
Satani je ota otito, yi o si sa gbogbo ipa re lati gbogun ti omo olorun. Ota yi o lo oniruru ohun ija ti o ba ri, a si rii pe oun ju okuta ti o ba wa ni arowoto. Sugbon kristeni ni lati se giri ki won mu okan le, ki won mase beru satani. Ohunkohun ko ye ki a rewesi ninu ise isin wa si olorun, a nreti wa ka mokan wa le, ki a di igbagbo wa mu titi de opin. Gbogbo onigbagbo ni lati ranti ileri kristi, fifun wa ni isegun lori gbogbo idojuko ninu aye.
ADURA
Jesu Kristi olufe, jowo so mi di alagbara, ki o si je ki ndi igbagbo mi mu titi dopin. Fun mi ni ore-ofe ati agbara lati bori alatako ati idojuko won. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
