TI OLORUN BA WA FUN WA
Awon eniyan ti o ba gbeke le Olorun yio je anfani abo re, won yio ni eri ti o dara lati pin pelu awon elomiran. Ikan ninu awon oluko orin Dafidi so pe iba ma se pe Oluwa ti o ti wa fun wa, ki Israeli ki o maa wi nisisinyi, iba ma se pe Oluwa ti o ti wa fun wa, nigba ti awon eniyan dide si wa, nigba naa ni won iba gbe wa mi laaye, nigba ti ibinu won ru si wa, nigba naa ni omi won-on-ni iba bo wa mole, isan omi iba ti bori okan wa. (Orin Dafidi 124:1-4)
EKO
Olorun njoba ni aarin awon omo re, yio si gbeja won ni gbogbo igba. Olorun yio ran angeli re lati dabobo awon omo re, yio dabobo won lowo ibi, yio si dari ese won, ki won ma baa subu. Nitorinaa enikeni ti yiogbe igbe aye asegun, o nilati je ogidi omo Olorun, ti o si ni igbekele ninu re.
ADURA
Olorun Olufe, mo fe abo ati ipese re. Jowo je ki n je omo re gidi. Je ki idapo mi pelu ki o se dede, ki igbekele mi wa ninu re titi aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
