OLORUN NDUNNU SI ISE RERE RE
Paulu gba awon ara Tesalonika niyanju ki won mase je Ole sugbon ki won fi iwa pele se ise won. Aposteli Paulu wipe, Nitori awa gburoo awon kan ti nrin segesege laarin yin ti won kii sise rara, sugbon won je atojubo ile kiri. Nje iru awon eni bee ni awa npase fun, ti a si nro ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki won ki o maa fi iwa pele sise, ki won ki o si ma je ounje, awon tikaraa won. Sugbon eyin ara, e ma se aare ni rere ise. (2 Tesalonika 3:11-13)
EKO
Ona Kristeni yi ko faye gba ole tabi imele, sugbon o fe ki a fi iwa pele se ise wa. Inu Olorun maa ndun lati ri awon omo ti won nse ojuse won si ebi ati awujo won. Eledaa yio bukun, yio si b’ola ati owo fun awon ti o ba fi iwa pele sise, ki awon eniyan lee fiwon se awo kose, ki won si tele won.
ADURA
Olorun Olufe, se mi ni Kristeni oniwa pele ti o nsise rere, ti o si npese fun ebi mi ati awujo. Bukun igbiyanju mi ti o dara, ki o si san esan fun mi, ki ise mi ki o so eso. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
