IBERU OLUWA
Iberu Olorun nmu ekunrere ibukun wa sinu aye Kristeni. Bibeli wipe ibukun ni fun gbogbo eni ti o beru Oluwa, ti o si n rin ni ona re, nitori ti iwo o je ise owo re, ibukun ni fun o, yio si dara fun o. Aya re yio dabi ajara rere eleso pupo ni aarin ile re, awon omo re yio dabi igi olifi yi tabili re ka, kiyesii pe, bee ni a o busii fun okunrin naa, ti o beru Oluwa. (Orin Dafidi 128:1-4)
EKO
Awon omo Olorun ni lati beru Olorun ni okan won. Ohun ti a le pe ni (amuyangan) iwa eni t o ba pe ara re ni Kristeni, ni a le pe ni iye iberu Olorun ti o wa ninu ojuse re.
Bi eniyan yio se ni aseyori si nile aye, o ni nse pelu bi a se beru Olorun si ni gbogbo akoko. Olorun yi o bukun gbogbo awon ti o ba ngbiyanju lati tee lorun. Eledaa yio ri daju pe gbogbo awon ti won nfi ojojumo sin in ni sise rere, won ko ni kabaamo, ni abe akoso bo ti wu ki o ri i.
ADURA
Olorun Olufe, ko mi bi mose le feran re ki nsi ni iberu re. Je ki nfi iberu re si ohukohun ti mo ba nse, ki emi lee se aseyege. Ran mi lowo lati lee bori idanwo, fun mi ni agbara fun ise ododo, ki emi lee je anfani re titi ojo aye mi gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
