OLORUN NFI OLA HAN AWON ENI TI O SIN OUN TOKANTOKAN
Ojo isiro ba awon Israeli lairo tele. Niwon bi Olorun ti ka abo re kuro lori won nitori ese, o rorun fun ota lati ona jijin lati ko lu won, won si ko ohun ini won lo. Awon ara Babeli tu Israeli ati Juda ka, won si ko awon eniyan wo inu igbekun lo si Babeli bi eru. O seni ni aanu wipe Israeli ti o tapa si Eledaa, iba maa gbe ni Babeli, ki won si ku sibe, bi ko se pe, won ri iyonu Olorun gba. Bibeli so nipa igbogun ti Jerusalemu – nje’ ni osu karun-un ni ojo kewaa osu, ti o je odun kokandinlogun, Nebukadnessari, Oba Babeli ni Nebusaradani, balogun iso, ti o sin Oba Babeli, wa si ile Jerusalemu, ati gbogbo ile titobi ni o fi ina sun. Ati gbogbo ogun awon ara Kaldea, ti won wa pelu balogun iso, wo gbogbo odi Jerusalemu lule yikaakiri (Jeremiah 52:12-14)
EKO
A pe awon omo Olorun lati bowo fun Olorun, ki a b’ola fun Olorun ki a mase rii fin. Bi idapo baba si omo se wa laari wa pelu Olorun, ko tumo pe ki a ma mo ipo wa. Lotito Oun ni Baba wa, sugbon O je Baba wa ti orun, a ko le fi we baba wa, sugbon o je Baba wa ti orun, a ko le fi we baba wa ti aye. O je Olorun ti o ga julo, o dara si awon omo re, sugbon o buru si awon ota re. Ni Pataki Olorun korira ese, ko si ni gba fun awon ti o muu ni yepere. Olorun mo riri awon ti o ni okan irele. Yio b’ola fun awon ti o nfi otito sin in, ti won si ntele ofin re. Nitori idi eyi, onigbagbo nilati maa rin deede niwaju Olorun, ki o ba le so ibukun re di pupo ninu aye wa.
ADURA
Olorun Olufe, gbin eru re sinu okan mi, ki emi mase se si o mo. Mase je kin mu ore-ofe igbala re pelu owo yepere ki a maa baa je mi niya. Fi ifami ororo yan mi ki emi le sin o ninu ara, okan mi, ki ijosin mi si se itewogba niwaju re, ki emi si ye fun gbigba ibukun re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
