IKIYESARA LATI KO AWON EKO EKE
Aposteli Paulu ro awon Tesalonika ki won di igbagbo ati asa Kristeni ti orun nbere mu. Paulu wipe nitori naa ara, e duro sinsin, ki e si di eko won-on-ni mu, ti a ti fi ko yin, yala nipa oro, tabi nipa iwe wa (2 Tesalonika 2:15)
EKO
Ewa Kristeni ni lati duro ninu igbagbo ti o jinle ninu iwe mimo. Kristeni ni lati kiyesara ki won mase faye gba eko eke, ti ko ni ibamu pelu bibeli. Bi o ti wu ki eko kan se le dun to leti, ti ko ba ti ni ifese mule pelu bibeli, a ko gbodo gbaa. Gbogbo omo Olorun nilati kiyesara, ki a mase gba pe gbogbo (soro soro) oro to dun ni oro Olorun.
ADURA
Olorun Olufe, mase je ki ese mi ye, je ki nduro ninu eko ti o wa ni ibamu pelu bibeli. Mase je kin se arifin si oro re, je ki emi lee duro ninu ofin re, ki emi lee se rere. Fun mi ni ebun dida emi yato, kin le duro ninu otito. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
