GBE OJU LE OLORUN
Omo eniyan le ja ara won kule, sugbon Olorun ko ni ja enikeni kule. Nitori naa, gbogbo eniyan ni lati fi igbekele won sinu Olorun, bi a ti mo pe, ko lee jawa kule. A le keko ninu orin Dafidi, emi o gbe oju mi si ori oke won-on-ni, nibo ni iranlowo mi yio ti wa? Iranlowo mi yio ti owo Oluwa wa ti o da orun ati aye. (Orin Dafidi 121:1-2)
EKO
Olorun nse abo ti o daju yi awon eniyan mimo re ka, yio gbeja awon ti o ba gbeke lee. Jehofa yio dabobo awon omo re, yio si pese fun aini won, ki gbogbo eniyan le ri didara re ki a si maa yin oruko mimo re. A ro gbogbo eniyan lati mu igbagbo won ninu Oluwa duro sinsin, ki a si ni idapo to dara pelu re.
ADURA
Olorun Olufe mo ni igboya pe iwo ni alagbara, ti o si po ni ipa mo jewo igbekele mi ninu re, mo si mo wipe o o ba gbogbo ireti mi pade. Iwo yio bukun mi, oo si fun mi ni isegun lori gbogbo igbenija ti mo ba ni, mo ti pinu lati fe o, emi o si maa sin o titi aye. Jowo fun mi ni ore ofe lati sise iranse mi pelu otitio ki emi si maa layo ninu si sin o. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
