SORA FUN IMORAN BUBURU
Rehoboamu tele imoran ti o buru, eyi mu ki o padanu ju abo ijoba nla ti o jogun lowo baba re Solomoni. Rehoboamu ko imoran awon agba, sugbon o gbo ti awon odo bi tire, ti won muu sina. Bibeli wipe ‘Reboboamu si lo si Sekemu, nitori gbogbo Israeli ni o wa si Sekemu lati fii je oba. O si se, nigba ti Jeroboamu, omo Nebati ti o wa ni Egipti sibe gbo, nitori ti o ti sa kuro niwaju Solomoni Oba, Jeroboamu si jokoo ni Egipti. Won si ranse pee, ati Jeroboamu ati gbogbo ijo Israeli wa, won si so fun Rehoboamu wipe, Baba re so ajaga wa do wuwo: nje nitori naa, se ki isin baba re to o le ati ajaga re to o wuwo ti o fi si wa ni orun, ki o fere die, awa o si sin o. O si wi fun won pe, E lo na titi di ijo meta, nigba naa ni ki e pada to mi wa. Awon eniyan naa si lo. Rehoboamu Oba siba awon agbaagba, tii maa duro niwaju Solomoni baba re, nigba ti o wa laaye, gbimo wi pe, imoran kin ni eyin da, ki emi ki o le da awon eniyan yii lohun? Nwon si wi fun fun pe, bi iwo o ba je iranse fun awon eniyan yi lonii, ti iwo o si sin won, won o se iranse re titi lae. Sugbon o ko imoran awon agbaagba ti won baa da, o si ba awon ipere ti won dagba pelu re, ti won si duro niwaju re gbimo. O si wi fun won pe, imoran kin ni eyin da ki awa ki o le da awon eniyan yii lohun, ti won ba mi so wipe se ki ajaga ti baba re fi si wa lorun, ki o fuye die. Awon ipere ti o dagba pelu re wi fun fun pe, bayii ni ki iwo ki o wi fun awon eniyan yii ti won ba o so wipe, baba re mu ki ajaga wa di wuwo, sugbon iwo mu ki o fuye die fun wa, bayii ni ki iwo ki o so fun won, omodirin mi yio nipon ju egbe baba mi lo. Nje nisinsinyi, baba mi ti gbe ajaga wuwo ka yin, emi o si fi kun ajaga yin, baba mi ti fi pasan na yin, sugbon emi o fi akekee na nyin. Bee ni Jeroboamu ati gbogbo awon eniyan naa wa sodo Rehoboamu ni ijo keta gege bi oba ti da wipe, e pada to mi wa ni ijo keta.
Oba si da awon eniyan li ohun ako, o si ko imoran awon agbaagba ti won baa da. O si so fun won gege bi imoran awon ipeere wipe, Baba mi mu ki ajaga yin ki o wuwo, emi o si bu kun ajaga yin, baba mi if pasan na yin, sugbon akekee ni emi o fi na yin. Oba ko si fi eti si ti awon eniyan naa, nitori ti Oran naa lati owo Oluwa wa ni, ki o le mu oro re se, ti Oluwa ti owo Ahijah, ara Silo so fun Jeroboamu, omo Nebati bee ni nigba ti gbogbo Israeli rii pe, Oba ko feti si ti won, awon eniyan naa da Oba ni ohun wi pe, ipin kin ni awa ni ninu Dafidi? Bee ni awa ko ni ipin ninu Omo Jese: Israeli, e pada si ago nyin, nje maa boju to ile re. Dafidi! Bee ni Israeli, pada sinu ago won. Sugbon awon omo Israeli ti ngbe inu ilu Juda wonni, Rehoboamu joba lori won. (Awon Oba 12:1-17).
EKO
Awa omo Olorun ni lati sora ki a gbadura dara dara Lori gbogbo imoran ti a ba gba, ki a ma baa gbe igbese odi ti yio mu wa se asise. Ki Kristeni mase tele imoran kankan laije pe a ti yeewo ninu adura. Ki a mo daju pe kii se gbogbo igbani niyanju ni o wa latiokan mimo. Opo imoran lo wa latiokan, imotara eni nikan, ki o ba lee mu eniyan kuna. Ni afikun, ki omo Olorun mase gba imoran ti yio siwon lona. Ki Kristeni ki o maa gba imoran lati odo Kristeni elegbe won. Pataki ni ki Kristeni ti o ba nfe imoran Olorun, ki o gbadura lati rii gba lati owo Emi Mimo, niwon bo se je pe oun ni agbani nimoran to ga ju.
ADURA
Olorun Olufe, jowo dari mi ki nma se wa imoran lo sodo alaigbagbo eniyan. Dari mi sodo onimoran ti o peye, ti yio to mi lati le gbe igbese to dara. Ran mi lowo lati lee gbadura lori imoran, ki emi to gbe igbese. Mase je ki n sare se idajo, ki emi ma baa kabamo nikehin. Dipo eyi, je ki Emi Mimo re fi mi lokan bale, wo mi ni agbara, kin le se ohun ti o to ti yi o mu aseyori ba mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
