IHUWASI SI AWON IRANSE OLORUN
Obirin opo kan se itoju wooli Elija, o si di oloro lehin bee. Opo yi tiro tele pe, oun ati omokunrin re yi o ku sinu aini, sugbon itan aye re yipada logan ti oran iranse Olorun lowo. Bibeli wipe oun si dide, o si lo si Sarefati. Nigba ti o si de ibode ilu naa, kiyesii obinrin opo kan nsa igi jo nibe, o si ke sii, o si wipe, Joo bu omi die fun mi wa ninu ohun- elo, ki emi ki o lee mu. Bi o si tin lo buu wa, o ke sii, o si wipe, Joo, mu okele ounje die fun mi wa lowo re. Oun si wi pe bi Oluwa Olorun re ti wa, emi ko ni akara, sugbon ikunwo iyefun ninu ikoko ati ororo die ninu kolobo si kiyesii, emi o si pese re fun mi, ati fun omo mi, ki awa le jee, ki a si ku, Elija si, wi fun pe, maa beru, lo, ki o si se gege bi o ti wi, sugbon ki o teteko se akara kekere kan fun mi ninu re naa, ki o si mu un fun mi wa, leyin naa ki o se tire ati ti omo re. Nitori bayi ni Oluwa Olorun Israeli wi, ikoko iyefun naa ki yio sofo, bee ni kolobo ororo naa kii yio gbe, titi di ojo ti Oluwa yio ro ojo si ori ile. O si lo, o se gege bi oro Elija, ati oun ati obinrin naa, ati ile re je ni ojo pupo. Ikoko iyefun naa ko sofo, bee ni kolobo ororo nana ko gbe, gegebi oro Oluwa, ti o ti pase Elija so. (1 Awon Oba 17:10-16)
EKO
Ohun rere ni lati bukun iranse Olorun, awon ti o ba nse bee yi o ri ekunrere ibukun gba lati odo Olorun. Niwon bi oruko Olorun ni asopo pelu iranse re, oun wa pelu won, enikeni ti o ba bukun won, yi o ri ibukun gba. Bakanaa enikeni ti o ba tako won, yi o jiya pupo. Jehofa yi o tako enikeni ti o ba tako awon iranse re.
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe iwo yio bukun mi bi mo ba b’ola fun awon iranse re, iwo yio fiya je mi bi mo ba ri won fin. Jowo ran mi lowo lati sora bi mo se nhuwa si won. Je ki nbowo fun won, ki nsi pese fun won. Fun mi ni ore-ofe lati ranti iranse re ninu adura. Jowo bukun mi bi mo se ntoju awon iranse re ni aye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
