NJE OLORUN LE FOKAN TO O PELU ORO?
Jobu (ninu bibeli) je oloro ti a le pe ni bilonia ni akoko wa yi. Olorun yi ko je ki oro re foo ni oju sugbon o sin Olorun ni otito. Bibeli salaye Jobu bi olotito eniyan ti o feran Olorun tokantokan, ti o fi gbogbo okun re sin Olorun. Bibeli so nipa Jobu wipe Okunrin kan wa ni ile Usi, oruko eni ti ije Jobu, okunrin naa si se olooto, o duro sinsin, eniti o si beru Olorun, ti o si korira iwa buburu. A si bi omokunrin meje ati omobinrin meta fun. Ohun osin re si je eedegbaarin agutan, ati egbedogun ibakasie ati eedegbeta ajaga oda maaluu ati eedegbeta abo ketekete, o si po ila-oorun lo. Awon omo re a si maa lo jeun are ninu ile ara won olukuluku ni ojo re, won a si maa ranse pe arabinrin won meteeta lati jeun ati lati mu pelu won. O si se nigbati ojo are won pe yika, ni Jobu ranse lo ya won si mimo, o si dide ni kutukutu owuro, o si ru ebo sisun niwon iye gbogbo won, nitori ti Jobu wipe, Boyaawon omo mi ti se, won ko si sope fun Olorun lokan won. Beeni Jobu maa nse nigba gbogbo.
EKO
Omo Olorun le je Oloro ki won so fi otito sin Olorun. A le tele Jobu (Jobu 1:1-5) ti o sin Olorun ninu otito pelu Ola re. Ni afikun, yio na wa ni suuru late lee sin Olorun ni otito ninu Ola wa. Eni bee yi o gbe Olorun ga ju ife ti ara re lo. Ni oro kan, ki Kristeni ti o ba fe do Okoro ki o bi ara re wo nipa ifokan tan. Oye ki o beere, ‘Nje Olorun Lee gbeke le mi, bi mo ba di Oloro tan? Olorun yio bukun enikeni ti o pinnu lati maa sin pelu okan otito.
ADURA
Olorun olufe, jowo se mi ni Kristeni ti yio se fi okantan ti kii se onimotara eni nikan, tabi eni ti oro lee bo loju. Fun mi ni okan ti yio ka o si saaju ohun gbogbo lo, ran mi lowo lati sin o ninu okan funfun, ki emi lee je oro re fun igba pipe. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
